Libya: Aadọrun atipo ri somi

Oko oju omi lori okun ni orile ede Libya Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ogunlogo awọn eniyan lo n gba ori okun Libya k'oja si ile Yuroopu

Awọn atipo to n lọ bi aadọrun ni wọn ti ri s'omi lẹyin ti ọkọ oju omi ti o n gbe wọn kuro ni bebe orilẹede Libya. Igbimọ gbogboogbo ti orilẹ-ede agbaye (UN) ti o n ri si eto irinajo lo sọ bẹẹ.

Awọn mẹta ti wọn yọ ninu ewu naa sọ pe ọpọlọpọ awọn ti o ri s'omi jẹ ọmọbibi orilẹ-ede Pakistan.

Orilẹede Libya jẹ oriẹede ti awọn atipo ma n gba kọja lati de ilu afojusun wọn ni ilẹ Yuroopu.

Ni ọdun to koja, agbajọ awọn orilẹede alawọfunfun f'ẹnuko lati pese iranlọwọ fun ile-isẹ to n seto ibodeti ilu Libya, lati da ọkọ oju omi ti o gbe awọn aṣikiri ati awọn asasala lọ si orilẹede Italy.

Awọn ajọ isọkan agbaye (UN) fi ẹsun kan awọn ijọba ilẹ Yuroopu pe wọn ko kọ'bi ara si ọrọ naa.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Orilẹede Libiya ti jẹ ọnọ pataki awọn aṣikiri ti n gbiyanju lati de okun gusu ilẹ Yuroopu lati ori okun.

Ajọ Amnesty sọ pe awọn alaṣẹ orilẹede Yuroopu ni aiṣedeede pẹlu awọn aṣikiri ati awọn asasala ni Libya.

"Awọn eniyan mẹwa ni wọn sọ pe wọn ti ba okun lọ".

Agbẹnusọ kan sọ pe awọn ọmọ ilu Pakistani n ṣe igbiyanju lati ṣe irinajo ti o lewu lati k'ọja si orilẹede Italy.

Akọroyin fun BBC ni ẹkun Gusu Afrika, Dan Jawad sọ pe ogunlọgọ awọn ọmọ orilẹede Libya wa lara awọn ti o ku ati awọn ti o yọ ninu ewu naa.