Yemi Osinbajo: 'Orilẹede Naijiria n sọ ẹlẹwọn di ẹranko'

Ọjọgbọn Yẹmi Osinbajo Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Igbakeji Aarẹ orilẹede Naijiria sọ pe Naijiria n sọ ẹlẹwọn di ẹranko

Igbakeji Aare orilẹede Naijiria ti bu ẹnu ẹtẹ lu ile isẹ ti o ns'eto awọn ile-ẹwọn lorilẹede yi - wi pe awọn ipo ẹwọn buru jayi - ti o sọ awọn ẹlẹwọn "ẹranko".

Ọjọgbọn Yẹmi Osinbajo sọ ibanujẹ rẹ lẹyin abẹwo rẹ si ile ẹwọn kan n'ilu Port Harcourt, eyi ti ijọba kọ lati gba awọn ẹlẹwọn ẹgbẹrin, ṣugbọn nisisiyi o ni marun ẹgbẹrun ẹlẹwọn lọ.

Iwe irohin Vanguard sọ pe aridaju wa pe bii ẹgbẹrun mẹrin ninu wọn ni awọn ti wọn wa ninu itubu ni wọn n duro de idajọ - awọn kan sọ fun igbakeji aarẹ wipe awọn ti n duro de idajọ nile ẹjọ fun bii ọdun marun.

Osinbajo, ti o se abẹwo ọgba ẹwọn naa ni ọjọru, sọ oju abẹ n'iko nibi ifilọlẹ iwe kan nipa awọn ipo ẹwọn jakejado orilẹ-ede.

"Ohun ti mo ri jẹ nnkan ibanujẹ nitori pe ko si iyẹwu ninu awọn ile-ẹwọn mọ sugbon o dabii ile itaja ti a ha awọn eniyan ti o ju ẹgbẹrun marun lọ si dipo awọn ẹlẹwọn ẹgbẹrin ti wọn kọ ibẹ fun".

Nipa iwadi mi, wọn wipe ko si aaye fun ẹlẹwọn nibẹ mọ, ẹnikẹni ti ba o lọ sibẹ yoo pada wale bi ẹranko."

Osinbajo daba pe eto lati se atunto si isẹwọn yoo gba akoko pupọ, ṣugbọn ko tilẹ si eto lati mu ipo naa dara rara.