Isinku Alex Ekwueme waye nipinlẹ Anambra

Oloogbe Alex Ekwueme Image copyright AFP/BBC
Àkọlé àwòrán Bi onirese Alex Ekwueme ko ba fin igba mọ, eyi to ti fin silẹ ko lee parun.

Etò ayẹyẹ ìsìnkú Alex Ekwueme tó jẹ́ igbákejì àárẹ àkọ́kọ́ fún orílẹ̀èdè Nàìjíríà ti wáyé lónìí ní ìpínlẹ̀ Anambra.

N'ibi ayẹyẹ yi, ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti yi orukọ ile ẹkọ giga fasiti ti ipinlẹ Ebonyi, Ndufu-Ikwo pada si orukọ, ilẹ ẹkọ giga fasiti ti Alex Ekwueme.

Igbakeji Aarẹ, ọjọgbọn Yẹmi Osinbajo kede eyi ni oko, Ipinle Anambra ni akoko isinku Alex Ekwueme, ti o jẹ igbakeji aarẹ ti Naijiria laarin ọdun 1979 ati 1983.

Osinbajo sọ pe Aarẹ Muhammadu Buhari ti fi asẹ si iyirukọ pada yi, ti o si wipe eyi ni lati bu ọla fun Alex Ekwueme fun awọn iranlọwọ rẹ si idagbasoke orilẹ-ede Naijiria.

Awọn eniyan jankan-jankan ni o peju-pesẹ sibi ayẹyẹ isinku yi.

Ẹ wo awọn aworan wọnyi:

Àkọlé àwòrán Awọn eniyan jankan-jankan ni o peju-pesẹ sibi ayẹyẹ isinku yi
Àkọlé àwòrán Ekwueme jẹ igbákejì àárẹ àkọ́kọ́ fún Nàìjíríà láàrin ọdún 1979 sí 1983
Àkọlé àwòrán Ekwueme dágbére fáyé lọ́jọ́ ìkọkàndìnlógún, oṣù kọkànlá, ọdún 2017 lẹ́ni ọdún máàrúnlélọ́gọ́rin