Buhari: Naijiria ko kabamọ lilewaju fun ijijagbara South Africa

asoju ijọba orilẹede South Africa si Naijiria, Lulu Loius Mnguni ati Aarẹ Buhari Image copyright @GarShehu
Àkọlé àwòrán Ọpọlọpọ inawo ati inara ni Naijiria na si ijijagbara orilẹede SouthAfrica

Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti sọ wipe, nkan diẹ kọ ni orilẹede Naijiria padanu lasiko to fi n lewaju ijijagbara kuro labẹ ijọba amunisin ni orilẹede South Africa.

Aarẹ Buhari ni bi o ti wu ki awọn ohun to fi jin fun ijijagbara orilẹede South Africa o pọ to, orilẹede Naijiria ko kabamọ lori ipa to ko.

Buhari salaye ọrọ yii lasiko to fi n gba alejo asoju ijọba orilẹede South Africa si Naijiria, Lulu Loius Mnguni to wa dagbere fun-un lati pada si orilẹede rẹ lẹyin ti saa isẹ rẹ pari.

Aarẹ Buhari ni orilẹede Naijiria ko ni wa ọwọ ajọsepọ rẹ pẹlu orilẹede South Africa ku.

Lulu Loius Mnguni, ninu ọrọ rẹ ni awọn iranti rere nipa orilẹede Naijiria kun awọn ohun meremere ti oun n mu pada lọ si orilẹede South Africa.