Ileesẹ aarẹ: Ẹyin oniroyin leku ẹda to n da wahala silẹ

Aarẹ Buhari Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Oniruru ẹhonu lo ti waye lori iha ti Aarẹ Buhari kọ si bi awọ̀n darandaran fulani se n pa awọ̀n eeyan lawọ̀n ipinlẹ̀ kanipaniyan lawọ̀n

Ileesẹ aarẹ lorilẹede Naijiria ti fi ẹsun kan awọn oniroyin wipe awọn gan an lo n fẹ wahala agbẹ ati awọn darandaran fulani loju ti ina rẹ fi n jo mọọ.

Agbẹnusọ fun ileesẹ aarẹ, Garba Shehu lasiko to fi n ba awọn oniroyin to wa nile'jọba apapọ Naijiria nilu Abuja s'ọrọ lo gbe ẹsun yii kalẹ.

Ileesẹ aarẹ orilẹede Naijiria ni ọkan-o-jọkan iroyin kobakungbe ti o n jade lati ọwọ awọn akọroyin lo n fun awọn ọrọ ikorira eleyi to ni o tubọ n fẹ ikọlu naa loju sii.

Ọgbẹni Garba Shehu s'alaye fawọn oniroyin to wa nibi ipade naa wipe awọn ofin ati ilana to de isẹ iroyin kikọ ti wọn ti pa ti si ẹgbẹ kan.

Image copyright AFP/Getty Images
Àkọlé àwòrán Wahala laarin awọn agbẹ olohunọsin ati darandaran fulani ti n mu ki ọpọ o kaya soke lori ọrọ aabo

"Ọwọja aibọwọ fun ilana ofin isẹ ikọroyin paapaa julọ lori ikọlu to waye nipinlẹ Benue jẹ ohun ti ko bojumu rara.

"Lilo awọn ọrọ ikorira lawọn iwe iroyin ati ori afẹfẹ paapaa awọn iroyin apilẹkọ jẹ ohun ti o n kọ ọpọ lominu.

"Gbogbo awọn to nlu ilu koya-koya ni lati ranti ohun to sẹlẹ ni orilẹede Rwanda saaju ogun abẹle wọn ninu eyi ti ọpọ ẹmi ti sọnu pẹlu awọn ọrọ ikorira to saaju rẹ."

Agbẹnusọ ileesẹ aarẹ tun salaye siwaju sii wi pe, "Ojuse aarẹ Buhari ni lati daabo bo ẹmi ati dukia gbogbo leyi ti o si ti nse ni ipinlẹ Benue ati kaakiri tibu-toro orilẹede yii.

Image copyright AFP/Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọpọ lo nkọminu lori iha ti ijọba nkọ si gulegule awọn darandaran fulani

Bi eniyan kan ba wa n pe aarẹ ni apaniyan, eyi ku diẹ kaa to, ko si fi ọwọ fun aarẹ, nipataki julọ lẹyin to ti kọ iwe sọwọ si ile asofin agba lori awọn akitiyan rẹ lati pa ina dukuu to nwaye ni ipinlẹ Benue.

Nigba ti awọn akọrọ beere pe bawo lo se jẹ wipe aarẹ ko pasẹ ki wọn ko ọmọogun lọ si Benue ayafi lẹyin igba ti wọn pa awọn fulani meje ni ilu Gboko, agbẹnusọ fun ileesẹ aarẹ dahun wipe minisita fun eto abo, Mannir Dan-Ali lo lee dahun rẹ.

Wahala ipaniyan ti ọpọ ti so kọ awọn darandaran fulani lọrun lorilẹede Naijiria ti ran ọpọlọpọ lọ sọrun ọsan gangan sugbọn eyi peleke to si gba agbada iroyin lagbaye kan pẹlu pipa ti awọn eeyan kan ti wọn funra si wi pe wọn jẹ darandaran fulani pa mẹtalelaadọrin eniyan ni ipinlẹ Benue.