BBC Yoruba, awa gaangan lara

Awọn osise BBC Yoruba lẹnu ise wọn
Àkọlé àwòrán,

A sẹ awa naa lee ni BBC tiwa

"A sẹ awa naa lee ni BBC tiwa. Eyi ga o. BBC Hausa, Swahili ati bẹẹ lọ la maa n gbọ po wa fun ọpọlọpọ ọdun. Asiko si ti to bayi tileesẹ agbohunsafẹfẹ BBC yoo da oju opo Yoruba silẹ. Fun iru ede to rẹwa, to si yaayi lati sọ, bii ede wa yi, ohun to rọrun lati foju sọna fun ni eyi."

Eyi ni awọn ọrọ Senator Rashidi Ladọja, tii se gomina tẹlẹ nipinlẹ Oyo, eyi to jẹ ipinlẹ kan lẹkun iwọ oorun guusu Nigeria, tọpọ eeyan ti n sọ ede Yoruba.

Ero Sẹnatọ Ladọja yi lo se afihan bi ireti awọn ọmọ ilẹ Kaarọ oo jiire se jinlẹ si nipa agbekalẹ oju opo BBC Yoruba, se tiwa n tiwa, akisa ni ti aatan.

Owe yoruba kan lo ni "Gele ko dun, bii ka mọọ we, ka mọọ we, ko dabi pe ko yẹni, ko tun wa yẹ ni ,ko dabi pe ko jẹ tẹni"—Itumọ eyi ni pe, agbekalẹ oju opo BBC Yoruba ko rẹwa to bii ki awọn eeyan tẹwọ gbaa. Eyi si jẹ anfaani nla lati kan si ọpọ eeyan ni ede abinibi wọn. Igbesẹ yi yoo tun fun awọn Yoruba lanfaani lati lẹnu ninu ileesẹ agbohunsafẹfẹ BBC.

Oju opo ikanni BBC Yoruba yi yoo tun se agbekalẹ itumọ to yanranti fun igbe aye, asa, ise,ajọdun ibilẹ, owe ati bẹẹ bẹẹ lọ, laarin awọn iran Yoruba. Igbe aye awọn eeyan yoo si tubọ pegede sii , tileesẹ iroyin kan ba n pese iroyin fun wọn ni ede abinibi wọn.

Àkọlé àwòrán,

BBC Yoruba n'iseju kan

Orisun isẹ iroyin tuntun.

Ẹni-ọwọ Henry Townsend se agbekalẹ ileesẹ itẹwe akọkọ lorilẹede Nigeria lọdun 1854, eyi to papa lo, lẹyin ọdun marun to se ifilọlẹ rẹ, lati fi tẹ iwe iroyin akọkọ lorilẹede Nigeria sita ni ede abinibi Yoruba,eyi to pe ni "Iwe Irohin Fun Awọn Ara Ẹgba Ati Yoruba". Ọjọ kẹtalelogun, osu kọkanla ọdun 1859 si ni iwe iroyin akọkọ naa jade . Lẹyin ifilọlẹ naa ni wọn wa pe orukọ rẹ ni "Iwe Irohin".

Amọ, wọn ni Ọba mẹwa, igba mẹwa, bi aye ba nyi, o yẹ ka maa ba aye yi ni. Pepele iroyin lorilẹede Nigeria ti yipada pupọ bayi kuro ni ti aye atijọ, ọpọn iroyin ti sun siwaju, amọ sibẹsibẹ awọn eeyan Yoruba si fẹ maa mọ ohun to n lọ. Wọn n garun, ti wọn si n kopa ribiribi, ti wọn ko si kawọ gbera rara lati mọ ohun to n sẹlẹ lawujọ wọn, paapa ni ede abinibi wọn..

Niwọn igba to si jẹ pe isu atẹnumọran kan kii jona, eyi lo sokunfa bibi oju opo BBC Yoruba bii ọmọ tuntun jojolo. Se ohun to ba si ti ya kan, kii tun pẹ mọ, Aaya ti wa bẹ silẹ, o ti bẹ sare bayi, ijiroro ati iroyin nipa asa ati oselu ti wa gba ọna ọtun yọ bayi, ọpọn ti sun.

Erongba fifun awọn eeyan ni iroyin ti wọn lee lo ( ni ede abinibi wọn), lo n mu ki iroyin naa sun mọ wọn pẹkipẹki, to si tun n jẹ ki wọn jẹ olotitọ si oju opo to n fun wọn ni iroyin naa kọja ero ẹnikẹni.

Àkọlé àwòrán,

Omi tuntun ti ru, ẹja tuntun ti jade

Isẹ Iroyin to ni Igbẹkẹle kikun

Niwọn igba to jẹ pe akọmọna ileesẹ agbohunsafẹfẹ BBC ni otitọ, orukọ rere ati aisegbe sibikan, eyiti oju opo BBC Yoruba yoo jogun, se ọmọ kii ba ipele iya rẹ, ko si asọ da, ko si aniani pe eyi yoo fun awọn Yoruba to jẹ ololufẹ oju opo yii lanfaani lati tẹwọgba ilana isẹ iroyin to se ara ọtọ, to si da lori igbẹkẹle awọn araalu. Biotilẹjẹpe o se ni laanu pe, akoko amulo oju opo ayelujara taa wa yi, n faaye silẹ fun itankalẹ iroyin eke ti ko fẹsẹ mulẹ, eyi to ti mu ki alafo nla wa laarin awọn iroyin to jẹ otitọ ati awọn araalu. Sugbọn, bi ẹkun pẹ lọ titi, ayọ n bọ lowurọ, pẹlu ifilọlẹ oju opo BBC Yoruba bayi, alafo naa ko ni pẹ dohun igbagbe.

Bẹẹni awọn osisẹ ti setan lati maa da bi ẹdun, rọ bii owe lori oju opo BBC Yoruba bayi.

Àkọlé àwòrán,

Isẹwa amojuto fini fini

Igbesẹ wa akọkọ

Wọn ni itọwo laa mọ adun ọbẹ, eto ifinimọle awa osisẹ gan ni itọwo akọkọ, eyi to fun wa loye lati mọ ohun ti ileesẹ agbohunsafẹfẹ BBC da le lori. Sise alabapade awọn oludanilẹkọ wa, fifi eti silẹ si idanilẹkọ wọn, ati fifi ara kinra pẹlu awọn akọroyin tuntun miran ti yoo maa sisẹ papọ loju opo BBC Yoruba lẹyinọrẹyin, wu ni lori pupọ. Lati ọjọ kinni ti gbogbo wa si ti foju kan ara wa, lati di "bi igbin ba fa, ikarahun a tẹle", taa si fọwọ sowọpọ lati sisẹ papọ. Eyi to wa jẹ oyin ninu rẹ ni igba ti wọn pin kaadi idamọ fun wa gẹgẹ bii osisẹ ileesẹ BBC, eyi lo wa fi idi rẹ mulẹ nitootọ pe osisẹ BBC ni wa. Se wọn ni, iborun ti ko ba sunwọn, abẹ abiya lo n gbe, eyi to ba sunwọn, ejika ni yoo wa, bi kaadi idamọ wa yi se sunwọn, lo mu kawa naa maa gbee kọrun kiri bii ami ẹyẹ goolu .

Ero wa gẹgẹbi osisẹ ileesẹ BBC

Lasiko taa bẹrẹ si ni ko eroja jọ fun ifilọlẹ oju opo BBC, ohun kan to se pataki taa se akiyesi rẹ ni pe ara awọn araalu n ya gaga lati ba wa sọrọ nitoripe ileesẹ agbohunsafẹfẹ BBC la ti wa. Wọn nigbagbọ pe a yoo sọ ohun ti wọn wi lai bomi laa. Koda, nigba ti iroyin awọn ọmọ Nigeria to ha sorilẹede Libya gbode, ileesẹ ti wọn gbe isẹ kiko awọn ọmọ Nigeria wale lati orilẹede Libya le lọwọ, mọọmọ kan si wa lati fun wa ni ẹkunrẹrẹ iroyin nipa iriri awọn ọmọ Nigeria, bẹrẹ lati akoko ti wọn n gbera lati orilẹede yi lọ si Libya, titi de igba ti wọn pada de.

Loni ni ọjọ ọla bẹrẹ.

Niwọn igba to jẹ pe ika to ba tọ simu, laa fi nre imu, ileesẹ BBC gba awọn osisẹ ti musemuse wọn da musemuse sẹnu isẹ. Awọn ọdọ tileesẹ BBC ko jọ lati maa se bẹbẹ loju opo BBC Yoruba yi yaayi pupọ nitori wọn ni ọgbọn atinuda lati da ara. Ohun ti yoo si ti idi rẹ yọ ni agbekalẹ awọn iroyin meriiri nipa awọn eeyan, latọwọ awọn eeyan ati fun awọn eeyan--Ẹ ma binu, o ka mi lara ni, o sa yẹ ki ohun ti mo n wi ye yin.

Ero awọn ikọ osisẹ BBC Yoruba

Adedayo Owolabi:

" Mo ri ileesẹ agbounsafẹfẹ BBC gẹgẹ bii ibudo atọnisọna taa ba n sọrọ nipa eto igbohunsafẹfẹ lode oni. Ileesẹ BBC ni orisun iroyin to jẹ ajaabalẹ, bii ẹmu ogidi, iroyin otitọ, ti ko ni ẹja n bakan ninu, ojulowo iroyin ti kii se ẹbu atawọn iroyin ti wọn ko bu omi la, ti ko si ni ẹlẹgbẹ. Koda, idanilẹkọ wọn gan ko ni orogun. Ojurere Ọlọrun ni lati jẹ osisẹ BBC."

Olubayọde Alebiosu:

"Isẹ akoroyin jẹ ara igbe aye mi. Atipe, lọwọlọwọ bayi, Ileesẹ BBC Yoruba ni aye mi".

Adedayo Okedare:

"Ala to wa si imusẹ ni bi mo se darapọ mọ ileesẹ agbohunsafẹfẹ BBC, koda gan, o tete wa si imusẹ ju bi mo se seto rẹ lọ. Bi BBC si se pe mi fun ifọrọwanilẹnuwo jẹ iwuri fun mi. Mo jẹ alabukun fun lati jẹ ara mọlẹbi BBC to gbooro."

Joshua Ajayi:

"Nigba ti mo gbọ pe ileesẹ agbohunsafẹfẹ BBC fẹ da oju opo yoruba silẹ, ọkan mi lọ sọdọ awọn babanla mi, ti wọn ko mọọkọ-mọọka lede oyinbo, ati ilakaka wọn lati gbọ ojulowo iroyin to wulo. Mo ni itara fun ipenija tuntun yi. Koda, nko lee mu ara ro mọ."

Busayọ Akọgun:

"Ibẹrẹ ọtun fun isẹ akọroyin ti mo yan laayo ni bi mo se darapọ mọ ileesẹ agbohunsafẹfẹ BBC jẹ. Nse lo dabi ala titi taa fi bẹrẹ isẹ. Koda, inu mi si n dun dẹyin."

Funmi Jokotade:

"Ala to wa si imusẹ ni bi mo se darapọ mọ ileesẹ BBC yi. Nko mọ pe o lee gba ọna yi yọ. Inu mi dun gidigidi."

Yetunde Olugbenga:

'"Nigba ti mo gbọ nipa agbekalẹ ikanni kan ti wọn pe ni BBC Yoruba, Mo ni whao, awọn tia ni eleyi. Se eyi wa lee jẹ ootọ bi lati ọdọ ileesẹ agba ọjẹ agbohunsafẹfẹ bii ti BBC? Sugbọn Ọlọrun nikan lo mu mi darapọ mọ wọn , ati pe emi ni mo n soju 'awọn tia'."