Idibo Burundi: Ijọba n yọ'wo osu oṣiṣe lati ṣeto l'ọdun 2020

Ẹto idibo nilẹ Burundi Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Awọn ajọ aseranwo lagbaye ti ko lati fun Burundi lowo fun ẹto idibo lọdun 2020

Ẹgbẹ osisẹ nilẹ Burundi n pariwo pe ki ijọba dẹkun yiyọ owo ninu owo oṣu awọn oṣiṣẹ.

Eyi waye lẹyin ti ijọba ilẹ Burundi ti bẹrẹ si nii yọ owo osu osisẹ lati seto idibo lọdun 2020.

O to idamẹwa owo osu awọn osisẹ ijọba ti wọn yoo maa yọ losọọsu.

O se e se ki awọn ọmọ ilẹ naa ti wọn ba n gba owo osu ti o to ẹdẹgbẹta lẹ ọgọta dọla losu padanu owo osu kan ninu owo osu wọn laarin ọdun kan.

Ẹgbẹ osisẹ nilẹ Burundi pẹlu pe wọn n se ijiroro pẹlu ijọba ti ni ki wọn dawọ yiyọ owo ninu owo osu osisẹ duro.

Awọn ajọ aseranwọ lagbaye kọ lati fun Burundi lowo fun eto idibo lọdun 2020 lẹyin igba ti aarẹ Pierre Nkurunziza so pe oun yoo du ipo aarẹ fun igba kẹta lọdun 2015.

Related Topics