West Ham gba'ṣẹ lọwọ Tony Henry lori ẹsun ẹlẹyamẹya

Aworan papa isere West Ham Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Saaju West Ham ti ni ki Tony Henry lo ro kun ni ile lori ọrọ ẹlẹyamẹya to so

Ẹgbẹ agbabọọlu West ham ti yọ alakoso rira ati tita agbabọọlu, Tony Henry lori pẹ o ni ẹgbẹ naa ko nii ra agbabọọlu ilẹ Afrika mọ.

Eyi waye lẹyin iroyin ti ile isẹ iroyin Daily Mail gbe jade pe Tony Henry sọ pe awọn agbabọọlu lati Afrika maa nfa wahala ti wọn ko ba mu wọn lati kopa ninu ifẹsewọnsẹ.

Ẹgbẹ West Ham ni awọn lodi si ọrọ ti o sọ ati wi pẹ iwadi todanmọran lawọn se lori isẹlẹ naa.

O fi kun wi pe ''West Ham ko nii gba iwa ẹlẹyamẹya laaye botile wu ko mọ"

Lọjọ ẹti ni akọni ẹgbẹ naa, David Moyes sọ wipẹ ọrọ naa ko ba agbabọọlu awọn ninu jẹ.

''Mo ti ba bi meji lara awọn agbabọọlu wa lati ilẹ Afrika sọrọ ko si wahala kankan. Wọn gbaradi daada. Ọkan wọn si balẹ pẹlu. Nnkan ti bẹrẹ si ni i lọ deede fun wa a si fẹ ki o maa lọ bẹẹ''.