Ajeponula: Òṣíkí kọja ọbẹ̀ lásán, kìí dá rìn láì mu òkèlè dání

Ajeponula: Òṣíkí kọja ọbẹ̀ lásán, kìí dá rìn láì mu òkèlè dání

Ọbẹ Ẹgusi jẹ ounjẹ pataki julọ ni Naijiria, gbogbo eniyan lo ni'fẹẹ

Ọpọlọpọ eniyan kundun ọbẹ ẹgusi pẹlu oriṣiriṣi ọna ti awọn eeyan maa n fi see.

Bi awọn kan ti n din ata ṣaaju ki wọn to da ẹgusi sii ni awọn miran n yan ẹgusi wọn ki wọn to fi se ọbẹ oṣiki yii.

BBC jade tọ alase Esther John lọ lati tun kọ ọna miran to rọrun lati fi maa se ọbẹ ẹlẹgusi paapaa lasiko ọdun yii.

Esther John to dantọ ninu ọbẹ sise ṣalaye kikun nipa awọn eroja fun sise ọbẹ ẹgusi bii: Ata, Alubọsa, ede, ẹja gbigbẹ, ẹfọ diẹ, epo pupa, iru, iyọ diẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Awọn ounjẹ bii Iyan to funfun lẹlẹ, fufu to rọ́ daadaa, ẹba ti ko ni koko ati awọn okele miran ni awọn eeyan fi maa n jẹ ọbẹ ẹgusi.

Bawo ni iwọ se fẹran ọbẹ ẹgusi tirẹ?