Miyetti Allah: A kò leè kọ̀wé sí Saraki nítorí a kìí ṣe olóṣèlú

Ẹgbẹ awọn darandaran lorilẹede Naijiria ti a mọ si Miyetti Allah ti yọ ọwọ ara rẹ kuro ninu ọrọ kan ti arakunrin kan ti o pe orukọ ara rẹ ni Garus Gololo, to jẹ ọmọ ẹgbẹ naa nilu Makurdi sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to si n ke si aarẹ ile aṣofin agba , Sẹnetọ Bukọla Saraki pe ko kọwe fipo silẹ.

Baba Uthman Ngelzarma to jẹ akọwe apapọ ẹgbẹ Miyetti Allah lorilẹede Naijiria ṣe apejuwe ọrọ naa gẹgẹ bii eyi to ku diẹ kaa to.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Atẹjade ti ẹgbẹ naa gbe sita ni ọjọọru sọ yanya pe, 'Miyetti Allah sọ laifọtape wi pe ọrọ ara rẹ ni Garos Gololo sọ nitori ko ni aṣẹ lati sọrọ lorukọ ẹgbẹ naa."

"Miyetti Allah kii ṣe ẹgbẹ oloṣelu a ko si lee ma tẹnubọ ọrọ awọn oloṣelu eleyi ti yoo tun maa pa kun wahala ati ipenija to wa nilẹ tẹlẹ."

Saraki, yára kọ̀wé fipò sílẹ̀ tàbí ká lé o - Miyetti Allah

Miyetti Allah ni, Saraki ko bojuto isẹ rẹ ni Ile Igbimo Asofin Agba, ati wipe, ko si ibasepo to gbooro laarin awọn asofin.

Ẹgbẹ naa ni Nàíjíríà nílò àwọn adarí tí ọ̀rọ̀ ìlú yóò jẹ lógún

Oríṣun àwòrán, Twitter/Bukola Saraki

Àkọlé àwòrán,

Àwọn ènìyàn ti fẹ̀sì lórí ẹ̀rọ ayélujára nípa ìdájọ́ iléẹjọ́ gígá wípé ẹ̀sún tí wọ́n fi kan ààrẹ ilé asòfin kò ní ẹsẹ̀ ńlẹ̀.

Ẹgbẹ awọn darandaran ni orilẹede Naijria, Miyetti Allah ti se ikilọ fun Aarẹ Ile Igbimo Asofin, Bukola Saraki, lati kọ iwe fi ipo rẹ silẹ ni kia mọsa tabi ki awọn fi ipa le e kuro ni ipo naa.

Adari gbogbo-gboo fun ẹgbẹ Miyetti Allah, Alhaji Garus Gololo fi ikilọ naa lede nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ ni Makurdi, nipinlẹ Benue.

Gololo ni Saraki ti se okunfa ọpọlọpọ isoro fun isejọba Aarẹ Muhammadu Buhari, to si mu ifasẹyin ba ọrọ aje ati ibagbepo awọn eniyan ni orilẹede Naijiria.

Àkọlé fídíò,

Bọlanle Ninalowo: Ọ̀rẹ́ lásán àti olóore mi ni Mercy Aigbe

Miyetti Allah ni, Saraki ko bojuto isẹ rẹ ni Ile Igbimo Asofin Agba, ati wipe ko si ibasepo to gbooro laarin awọn asofin, eleyii ti yoo se iranwọ fun bibu ọwọ lu awọn abadofin ni ile asofin.

O ni, orilẹede Naijria nilo awọn adari ti ọrọ awọn ara ilu yoo jẹ logun lati mu ibugboro ba igbe aye wọn.

Ti a ko ba gbagbe, laipe yii ni Aarẹ Ile Igbimọ Asofin Agba, Bukola Saraki pẹlu awọn asofin to le ni ogun, kuro ni ẹgbẹ oselu APC lọ si PDP.