Aisan Cancer pa ọkunrin kan lẹ̀yin ọjọ̀ díẹ̀ to jẹ milionu kan dọ́là

Àìsàn jẹjẹrẹ Image copyright Science Photo Library
Àkọlé àwòrán Àìsàn jẹjẹrẹ ti seku pa ọpọ eniyan

Arakunrin kan ti wọn pe orikọrẹ ni Donald Savastano ni ìbànújẹ́ ti pade ayọ̀ rẹ̀, nigba ti a gbọ pe o gbẹ́mìí mì lẹ́yìn ọjọ mẹ̀tadinlogun gééré to jẹ miliọnu kan owo dọ́là ninu ìyíkoto.

Arakunrin ọun, ẹni ọdun mọkanlelaadọta ni a gbọ́ pe o ti n ni awọn ipenija ilera ki o to di àsìkò ti ayẹwo fi han pe o ni aisan jẹjẹrẹ.

Wayi, ki o to di pe o jẹwó ninu iyikoto, Savastano ni a gbọ pe o jẹ kápẹ́ńtà, ti kò si ni owo tó tó lati tọju ara rẹ̀.

Sugbọn iroyin ibanujẹ ni o jẹ pe igba akọkọ ti arakunrin ọun o fojú ba ile iwosan fun itoju ni esi ayẹwo sọ pe o ni arun jẹjẹrẹ.

Image copyright Science Photo Library
Àkọlé àwòrán Aisan jẹjẹrẹ ko jẹ ki Savastano gbadun owo rẹ

Savastano ni a gbọ pe o ti siwaju asiko yii sọ fun ile ise iyikoto ọun pe owo ti oun jẹ ọun yoo yi ìgbé ayé oun pada patapata. O ni oun o ra ọkọ̀ àjàgbé kan, oun o si lọ fun isinmi.

O ni ìrọ̀lẹ́ ọjọ kan ti oun n lọ ile oun ni oun ri ipolowo iyikoto ọun ti oun si gbiyanju rẹ̀ wò, ko to wa di pe oun jẹ obitibiti owó. O fi kúun pe oun ko ni ero kankan lori ìfẹ̀yìntì oun ki o to di ìgbà náà.

A gbọ pe Savastano ati ọrẹbirin rẹ ọjọ pipẹ Julie Wheeler ni wọn jọ n gbe titi o fi di ọjọ iku rẹ.