Femi Falani: Awọn oniroyin lẹ́tọ̀ọ́ lati sọ̀ ero aráàlú

Femi Falana Image copyright @FALZtheBAHDGUYY
Àkọlé àwòrán Femi Falana ni o yẹ ki awọn ọmọ Naijiria mọ'yì ẹmi aọn eniyan.

Ogbontarigi agbẹjẹ́rò agba lorilẹede Naijiria, Femi Falana ti sọ pe oun ko faramọ bi aarẹ Buhari se n pasamọ pe awọn oniroyin n fẹ ọrọ loju lori awọn ohun to n lọ lorilẹede Naijiria.

Ninu ifọ̀rọ̀wanilẹ́nuwò kan pẹlu ile isẹ̀ BBC lori ẹrọ ibanisọrọ ni Falana ti sọrọ naa.

Falana ni aarẹ Buhari kò kọ iha to tọ si bi awọn ara ilu se n bu ẹnu atẹ lu ìsejọba rẹ̀. O ni awọn oniroyin lẹtọ lati fi ero ara ilu han lori bi ohun gbogbo se n lọ.

Falana ni aarẹ Buhari funrarẹ jẹ ọkan lara awọn eniyan ti wọn bu ẹnu àtẹ́ lu isejọba aarẹ ana Goodluck Jonathan ju.

O ni ìtanijí ni o yẹ ki ọrọ ti awọn eniyan n sọ jẹ fun isejọba Buhari.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Fẹmi Falana ko faramọ iha ti Buhari kọ si ọrọ awọn oniroyin

Wayi, Falana ni iwa aláìmọ̀kan ni bi awọn kan se n sọ pe aarẹ Buhari ko kọbiara si ipaniyan awọn Fulani darandaran nitori pe Buhari jẹ ẹya Fulani.

O ni ọ̀rọ̀ ti ko bojumu gbaa ni, nitori pe, kii se ninu isejoba aarẹ Buhari nikan ni wọn ti n pa awọn eniyan lorilẹ̀ede Naijira, o ni lati ọjọ pipe ni awọn ẹya kan ti n seku pa awọn ẹya miiran lorilẹede Naijiria, ti ilẹ ẹjọ yoo si tun da iru awọn ọdaran bẹẹ silẹ.

Falana ni ọna abayọ ti orilẹede Naijira ní ni lati fi ẹ̀mí ọmọniyan se.