Alaga ile ẹjọ CCT ni Nigeria gba abẹtẹlẹ lọwọ afurasi

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Wọn fi ẹsun abẹtẹlẹ kan Danladi Umar

Wọn ti fi ẹsun kan olori ile ẹjọ to ngbẹjọ awọn to di ipo nla mu lorilẹede Naijiria (Code of Conduct Tribunal), Danladi Umar pe o gba owo abẹtẹlẹ. Ajọ orilẹede Naijiria to ngbogun ti iwa ibajẹ ati jẹgudujẹra, EFCC fi ẹsun kan adajọ naa pe o beere fun ẹgbẹgbẹrun owo dọla lọwọ afurasi iwa jẹgudujẹra kan.

Eyi kii se igba akọkọ ti wọn yoo fi ẹsun gbigba abẹtẹlẹ kan ọgbẹni Umar. O ti sẹlẹ ri ti wọn o le f'ogun rẹ gbari nigba kan ri ti nkan pa a pọ pẹlu aarẹ ile igbimọ asofin, ẹni to jẹ oloselu kẹta to lagbara ju lorilẹede Naijiria ti o da a silẹ ninu ẹsun jẹgudujẹra lọdun to kọja.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ajọ EFCC gbe Danladi Umar lọ sile ẹjọ

Wọn ti gbe ẹjọ naa lọ si ile ẹjọ giga kan.

Titi di akoko yii, ọgbẹni Umar ko tii fi ọrọ kankan silẹ. Ẹwẹ, aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti seleri lati fi opin si iwa jẹgudujẹra ati ọwọ ti ko mọ gẹgẹ bi o se wa ni aarin gbungbun awọn igbesẹ ipolongo aarẹ. Bi o ba le wu u ti gbongbo ti gbongbo, yoo jẹ aseyọri nla nitori iwa jẹgudujẹra ti di kokoro ajẹnirun to wa ni gbogbo ipele ilu.