Oluwo woju Ọọni niwaju awọn lọba-lọba

Ọọni ti Ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Itahunsira waye laarin Oluwo ti ilu Iwo, ati Ọọni ti Ile Ifẹ nibi ipade awọn lọba-lọba

Ipade awọn ori ade lorilẹede Naijiria waye ni ilu Port-Harcourt lọjọ isẹgun ọsẹ to kọja fẹrẹẹ ri idiwọ pẹlu idojukọra to waye laarin oluwo ti Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi ati olori ẹsọ Ọọni ti ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja keji.

Itahunsira yii waye ni ile igbalejo ti wọn npe ni Presidential Hotel, Port Harcourt. Bi kii ba se wipe adọgbọnsi ati ọgbọn ori ti wọn fi bọọ, ọrọ naa ko ba da yanpanyanri silẹ ni loju gbogbo eniyan.

Iroyin to ni leti wipe bi Ọọni Ifẹ se pari ọrọ idupẹ tan ti o npada lọ si aye rẹ ni olori ẹsọ rẹ ni wọn sọ wipe ọgbẹni Emmanuel Ọlawale Kọlawọle to dari awọn ẹsọ to ku fara gba Oluwo to da bi ẹni pe o ndi Ọọni lọna ati lọ jokoo si aye rẹ.

Nigba naa, wọn ni Oluwo nsọrọ pẹlu Minisita abẹle, ọgagun Abdulrahman Dambazzau ti wọn jọ wa lori tabili kan naa pẹlu Ọọni ati gomina ipinlẹ Rivers, Nyesome Wike.

Ẹni kan to soju rẹ koro to wa ni agbo ti Oluwo fi ẹsun kan olori ẹsọ naa wipe itara r ti pọ ju to se ndẹru bolẹ wipe yoo ti Oluwo bi ko ba yago fun Ọọni lati kọja. Wọn se lo kọ lati gbọ ti Ọba Akanbi ti o si ti i kuro lọna.

Sugbọn oluranlọwọ Ọọni lori ọrọ iroyin, Comrade Moses Ọlafare sọ wipe ko tilẹ si ohun to jọ mọ isẹlẹ yẹn to waye ni ilu PortHarcourt. Ọlafare sọ wipe o jẹ ojiji lati gbọ iru ohun to le si ni lọkan bayii nitori pe ko si ootọ kankan ninu rẹ.

Lara awọn alejo to wa nibi ipade naa sọ pe ifori ade tẹlẹ ni ki olori ẹsọ Ọọni layalaya lati ti Ọba onipo kini bii ti Oluwo kuro lọna.

Ẹwẹ, Kọlawọle naa yii pada wipe oun ko ti Oluwo tabi se e ni ohunkohun, bi o tilẹ jẹ wipe o gba wipe nkankan pa oun pọ pẹlu Oluwo lakoko to nse isẹ rẹ. O ni ko see se ki oun ri Ọba to ni iyi fin gẹgẹ bi ọmọ Yoruba gidi sugbọn oun si ni ojuse lati da abo bo ọga rẹ.

Emmanuel sọ wipe oun ko mọ nipe aawọ abẹlẹ kankan laarin Oluwo ati Ọọni tẹlẹ. O Sọ siwaju wipe " Eeyan wa ni wọn"

Ọlafare ninu esi rẹ fi kun un wipe o le ni ọgọrun awọn oniroyin ati o le ni ọgbọn ayaworan to wa nibi eto naa, o ni bi iru nkan bẹẹ ba sẹlẹ, o yẹ ki iroyin ti gbe e lati ọsẹ ti eto naa ti waye.

O sọ pe Oluwo kan tumọ ojuse olori ẹsọ Ọọni sodi lasan ni leyi to pọ̀n dandan fun un lati se fun ọga rẹ.

Ọlafare ni olori ẹsọ fi ọwọ sọ fun Oluwo lati jẹ ki Ọọni raye kọja si aye rẹ o si ni Oluwo gba lọgan, Ọọni si kọja si aye rẹ.