Abubakar Baraje: E ma gbiyanju lati yọ Saraki loye

Bukola Saraki Image copyright @bukolasaraki
Àkọlé àwòrán Braje ni ko sẹni to le yọ Saraki lóyè

Olóyè kan ninu ẹgbẹ́ oselu APC, Abubakar Baraje lo ti sọ pe àlá ti ko le sẹ ni erongba lati yọ̀ Bukọla Saraki gẹgẹ bi olori ile igbimọ asofin àgbà.

Baraje sọ̀rọ̀ ọun lanaa nigba ti o n ba awọn oniroyin sọrọ nilu Ilọrin lẹyin adura to waye fun ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ bi o se pe odun mẹtadinlaadọruun.

O ni awọn ti n gbọ firinfirin labẹ́lẹ̀ pe awọn kan n gbiyanju lati yẹ oju Bukola Saraki gẹgẹ bi adari ile igbimọ asofin.

O fi kun ọrọ rẹ pe erongba ọun jẹ eleyi ti ko fẹsẹ mulẹ, nitori awọn ti wọn n gbimọ yii ko ni ẹsun kan to gúnmó lati fi kan Saraki.

Baraje ti o jẹ olóyè tẹ́lẹ̀ ri ninu ẹgbẹ oselu PDP sọ pe, oun ati Saraki wa lara awọn ti wọn jẹ òpómúléró ẹgbẹ oselu APC lati igba ti wọn ti da ẹgbẹ ọun silẹ, ti o si jẹ pe awọn si n tẹ siwaju ninu kíkọ́ ẹgbẹ oselu ọun.

Baraje sọ pe Saraki jẹ ẹni ti awọn akẹgbẹ rẹ ni itẹriba fun.