'A ti pa Boko Haram run pataoata' - Ọmọ Ogun Naijiria

Ikọ̀ ọmọ ogun Naijiria
Àkọlé àwòrán Ikọ̀ ọmọ ogun Naijiria ni ki awọn ti wọn wa ni kọrọ jade wa

Ikọ̀ ọmọ ogun ilẹ Naijira ti sọ pe awọn ti lọ ikọ̀ Bokoharam ni àlọ̀mọ́lẹ̀ ti wọn n lọta o.

Olori ikọ̀ Operation 'Lafiya Dole', Rogers Nicholas lo sọ eyi nibi ìfilọ́lẹ̀ ikọ̀ ọmọ ogun apapọ orilẹede Naijiria ati orilẹede Cameroon ni ilu Maiduguru.

Nicholas ni awọn ti foju ikọ Shekau gbolẹ̀, ati pe awọn ti le ikọ Bokoharam jinna, awọn si ti tu ìpàgọ́ wọn ka. O ni eto kan ti ikọ̀ oun s'agbekalẹ̀ rẹ̀, ti wọn n pe ni DEEP PUNCH lo ti tu ipagọ awọn Bokoharam ka, ti awọn si ti gba ibudo wọn kan ti wọn n pe "Camp Zaro" ninu igbo Sambisa.

Àkọlé àwòrán Ikọ̀ ọmọ ogun Naijiria ni awọn ti lé ikọ̀ Bokoharam jinna

Nicholas fi kun ọrọ rẹ̀ pe, oun tó tó ọgórùún ọmọ ikọ Bokoharam ni wọn jọwọ ara wọn fun ikọ̀ ọmọ ogun ti ọpọ wọn si juba ehoro, nigba ti awọn da ọpọ eniyan to ti wa ninu igbekun awọn Bokoharam ọun silẹ.

O ni awọn ó lé awọn ikọ̀ agbesunmọmi ọun de ibikibi ti wọn ba lọ.

O wa rọ awọn ọmọ ikọ Bokoharam ati awọn ti wọn ji gbe ti wọn wa ni ipamọ lati jọwọ ara wọn fun awọn ọmọ ogun.