Babangida sọ pe Nigeria nilo oselu alatako to rinlẹ

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọgagun Ibrahim Babangida ni ki aarẹ Buhari fipo silẹ

Olori orilẹede yii tẹlẹ ri nigba ijọba ologun, ọgagun Ibrahim Babangida ti pe aarẹ Muhammadu Buhari lati fipo aarẹ silẹ ni ọdun 2019 ki ayipada iran le wa. O wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati fọwọsowọpọ pẹlu aarẹ titi saa rẹ yoo fi pari.

Ọrọ Babangida yii waye lẹyin ọsẹ meji ti aarẹ ana Olusẹgun Ọbasanjọ gba aarẹ Buhari nimọran lati ma lọ fun saa keji.

Fun Babangida, orilẹede Naijiria wa lagbede meji bayii. O wa diidi sekilọ wipe ohun ti awọn ọmọ Naijiria ba yan nipa ti adari ni yoo sọ bi ọrọ orilẹede yoo se ri nipa oselu, ọrọ aje ati ẹsin.

Nigba to woo pe orilẹede Naijiria lo pọ ju nilẹ Afrika, o ni o si nwa adari to dara ti yoo figagbaga pẹlu ayipada ọọrundun yii. Babangida gbagbọ pe agbara Naijiria wa ninu oniruuru ẹya ati ẹbun to wa lorilẹede yii.

O tẹsiwaju wipe "ni ọdun 2019 ati tayọ rẹ, o yẹ ka pawọpọ gẹgẹ bi ilu wipe a nilo awọn adari tuntun to niipa lati bojuto awọn nkan teleduwa fi jiiki wa ki a si bẹrẹ ilana fifi orilẹede yii si ibi giga pẹlu awọn adari igbalode ni ibamu pẹlu ayipada to nwaye ninu isejọba ode oni".

Pẹlu bi o se ku ọdun kan fẹẹrẹfẹ ti idibo gbogboogbo yoo waye, agba oloselu naa nireti wipe awọn araalu yoo yan ayanmọ wọn funra wọn lati dibo yan awọn adari tuntun.