Komisana ilera ni Ondo: Eku ọlọmu pupọ lo nfa iba Lassa

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEku ọlọmu pupọ lo nfa iba Lassa

Gomina Oluwarotimi Akeredolu ti ipinlẹ Ondo ti sọ pe lootọ ni aisan iba Lassa ti wọ ipinlẹ naa, o si ti mu ẹmi eniyan mẹsan

Bakan naa, Komisana fun eto ilera ni ipinlẹ naa, Dokita Abdulwahab Adegbenro nigba ti o mba ikọ iroyin BBC Yoruba sọrọ wipe aisan iba Lassa yii wọ awujọ wọn ni nkan bi ọsẹ melo kan sẹyin. Nigba ti wọn ri i pe o bẹrẹ si ni ran ka, ijọba ipinlẹ naa gbe igbesẹ kanmọ kanmọ lati tete kasẹ aisan naa nilẹ

O jẹ ko di mimọ wipe ipinlẹ Ondo ni odun gbogbo teeyan nilo lati tọju awọn to ba ni aisan naa ati pe fun awọn eleto ilera, ko sewu niwọn igba ti wọn ba wọ iru ẹwu to yẹ ki wọn wọ ki wọn to fọwọ kan alaisan iba Lassa.

Eku ọlọmu pupọ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn eku ọlọmu rọọrọ lo n fa iba Lassa

Wọn sọ pe awọn onisẹ igbohunsafẹfẹ ipinlẹ naa ti gbe iroyin pe mejilelọgọrun awọn isẹlẹ mii ni wọn ti ro pe o jẹ iba Lassa ni ijọba ibilẹ mẹjọ ni ipinlẹ naa.

Ẹwẹ, mẹrindinlogoji ninu mọkandinlọgọrin isẹlẹ yii ni wọn ti ni aridaju rẹ pẹlu iwadii nile iwosan to fi mọ eniyan mẹsan toku bayii.

Image copyright @RotimiAkeredolu
Àkọlé àwòrán Gomina Akeredolu sọ bi ipinlẹ Ondo se gbaradi lati tọju awọn alaisan iba Lassa

Gomina Akeredolu sọ nipa eto ti wọn ti se kalẹ fun awọn to ba lugbadi aisan naa:

·Awọn alaisan wa ni ile iwosan ijọba to wa ni Ọwọ fun ayẹwo gẹgẹ bi wọn se nse ni ile iwosan to wa ni Irrua, ipinlẹ Edo

· Ile iwosan mẹtadinlaadọrin ati ibudo ọọdunrun le mẹjọ kaakiri awọn ilu lo wa fun awọn ijọba ibilẹ ti aisan naa ti nja

·Igbaradi fun isẹlẹ pajawiri pẹlu ikọ fun eyi ti tunramu lawọn ijọba ipinlẹ lati kapa aranka aisan naa nipinlẹ Ondo

·Ipolongo ati ilanilọyẹ ti nlọ ni ipinlẹ naa nipa aisan iba Lassa

·Wọn ti gbe ọk silẹ ti yoo maa ko ayẹwo kiri atawọn alaisan ti wọn ba gbe lọ si ile iwosan Irrua ni ipinlẹ Edo.