CHAN 2018: Morocco gba'fe ẹyẹ, wọn lu Naijiria mọ'lẹ

Atlas Lions gbe ife ẹyẹ ninu idije CHAN Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Alakoso ere idije yọ ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles kan jade

Ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede Morocco, ti a mọ si Atlas Lions ti gbe'gba oroke nibi idije ti awọn agbabọọlu ti o gba bọọlu jun nilẹ Africa - (CHAN) lẹyin ti wọn se awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede Naijiria, Super Eagles ni ọṣẹ pẹlu ami ayo mẹrin si odo.

Idije asekagba naa waye lalẹ ọjọ aiku ni Casablanca tii se olu ilu Morocco.

Zakaria Hadraf jẹ amin ayo meji nigbati Walid El Karti ati El Kaadi gba ami ayo kọọkan wọ'le fun ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Morocco.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Idije asekagba naa waye lalẹ ọjọ aiku ni Casablanca tii se olu ilu Morocco

Ọdun 1976 ni Morocco ti gba ife ẹyẹ nilẹ Africa kẹyin.

Fun awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ti Naijiria, eyi jẹ nkan ibanujẹ gidi fun ẹgbẹ agbabọọlu ti o yanranti julọ nilẹ Africa ninu idije CHAN.