Jacob Zuma koju idojukọ lọwọ ANC

Aarẹ orilẹ-ede naa, Jacob Zuma Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Awọn alakoso igbimọ pe ipade pajawiri fun ọjọ aje lati jiroro lori Aarẹ Zuma

Awọn agbaagba olori ẹgbẹ oselu ANC ti orilẹede South Africa ti nfa aarẹ orilẹ-ede naa, Jacob Zuma lokun lọrun pe k'ofi ipo asiwaju ẹgbẹ ati aarẹ silẹ.

Ko tii si pato alaye nipa idi ṣugbọn awọn alakoso igbimọ ti pe ipade pajawiri fun ọjọ aje lati jiroro lori Aarẹ Zuma.

Wọn rọ ọgbẹni Zuma loye ni ọdun ti o kọja lẹyin awọn ẹsun iwa ibajẹ ti wn fi kan an, ti wọn si yan Cyril Ramaphosa rọpo rẹ gẹgẹ bi olori ẹgbẹ oselu ANC.

Awọn onisẹwe sọ pe wahala faa-kaja latari ipo asoju ati oludari ẹgbẹ oselu ANC ti n da ẹgbẹ oselu naa si meji ki eto idibo ti ọdun ti o n bọ too de.

Julius Malema, olori alatako ati ẹya ẹgbẹ oselu ANC atijọ, sọ lori opo ayelujara Twitter rẹ pe ọgbẹni Zuma ti kọ lati kuro nipo.

Aarẹ Jacob Zuma ti wa labẹ iwadi ati atako awọn ẹgbẹ oselu ni orilẹede South Africa lati igba ti o ti wa labẹ ẹsun fun iwa ibajẹ.