Boko Haram: Emi kan lọ, ọpọlọpọ f'arapa ninu ikọlu Kofa ni Maiduguri

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ikọlu yi n waye lẹhin ti ile isẹ ọmọogun orilẹede Naijiria ti figa gbaya wipe awọn ti bori Boko Haram.

O kere tan eniyan kan ti padanu ẹmi ti ọpọlọpọ miran si ti f'arapa ninu ibugbamu ikọlu Boko Haram n'ipinlẹ Borno.

Iroyin ti o tẹ wa lọwọ sọ wi pe awọn agbesunmọmi Boko Haram kọlu abule Kofa ti o wa ni adojukọ ibudo ifiniwọsi fun awọn ti isẹlẹ ṣi nipo ti Dalori n'ilu Maiduguri loru anọ.

Agbẹnusọ fun ajọ alakoso isẹlẹ pajawiri (sema) ti ipinlẹ Borno, Bello Dambatta fi idi ikọlu yi mulẹ pẹlu alaye wipe ogunlọgọ awọn eniyan miran ni wọn fi ara pa nigbati awọn agbesunmọmi Boko Haram ju inọ si awọn ile lorisirisi ninu abule naa.

Ikọlu yi n waye lẹhin ti ile isẹ ọmọogun orilẹede Naijiria ti figa gbaya wipe awọn ti bori Boko Haram.

Olori ikọ Operation 'Lafiya Dole', Rogers Nicholas sọ eyi nibi ìfilọ́lẹ̀ ikọ̀ ọmọ ogun apapọ orilẹede Naijiria ati orilẹede Cameroon ni ilu Maiduguru lọjọ aiku.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí