Idaamu darandaran: Ganduje pe awọn darandaran si Kano

Aworan olu ilu Kano Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ọpọlọpọ awọn olugbe ipinlẹ Kano jẹ Fulani darandaran

Gomina Abdullahi Umar Ganduje ti Ipinlẹ Kano sọ pe oun ni ọnọ abayọ fun orilẹede Naijiria ninu idaamu ati ijamba ti o n waye nitori ija laarin awọn darandaran fulani ati awọn agbẹ afoko-sọrọ jadejado orilẹede yi.

Ganduje ti wa ke pe gbogbo awọn Fulani ti o wa ni ipinlẹ miiran, paapa awọn ti ipinlẹ Benue ati Taraba, lati wa si ipinle rẹ ni Kano nitori ipinle naa ni ilẹ-ọsin pupọ lati gba wọn ati awọn ẹran wọn.

Gominọ Ganduje ti o jẹ Fulani funra rẹ, sọ eyi lakoko ti o nwo itọju ati ajẹsara ọfẹ fun awọn maluu ati awọn ẹranko kekere ti o to bii ẹẹdẹgberun ni ile-iṣẹ ti o wa ni agbegbe ijọba ibilẹ Garum Malam gẹgẹbi apakan ninu awọn iṣẹ isaami fun ọdun 2017/2018.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Gominọ pe awọn Fulani lati Benue ati Taraba nitori Kano ni ilẹ-ọsin pupọ lati gba wọn ati awọn ẹran wọn

Gomina naa tun sọ pe gẹgẹ bi ipinnu rẹ, ijọba setan lati ṣe atilẹyin fun dida ẹranko ni ipinlẹ Kano, atipe ijọba yoo tẹsiwaju lati maa pese awọn ile-iṣẹ ati awọn ohun amulo fun wọn ati awọn ẹranko wọn.

Ganduje tun sọ pe awọn Fulani ti wọn jẹjẹ ọmọbibi ipinlẹ Kano ko jade kuro ni ipinlẹ naa lọ si awọn ilu miiran nitoripe Kano ni ni ilẹ ti wọn fi n ṣe ounjẹ ati awọn ọpa ounjẹ ẹranko.

O sọ pe: "Nitorina, wọn ko ni idi kan lati jade kuro ni ipinle.

A n ṣetọju wọn ati pe a gba wọn ni ọwọ ati iyi ti o b'ojumu. "Mo n pe awọn darandaran lati gbogbo awọn ilu Naijiria lati wa si Kano nitori a ni awọn ohun eelo to pọ lati gba wọn. A ni awọn irugbin koriko ni agbegbe Rogo, Gaya, Kura, Tudun-Wada, Ungogo ati awọn ibi ipamọ miiran nibiti awọn ohun eelo wa lati gba awọn darandaran ati awọn ẹran wọn si. "

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ọpọlọpọ awọn olugbe ipinlẹ Kano jẹ Fulani darandaran

Alakoso fun eto ọrọ nipinlẹ Kano, Mahd Garba sọ fun BBC Yoruba pe Gomina n pe awọn darandaran gẹgẹ bi ọna lati pese ọnọ abayọ si wahala ati apaniyan awọn Fulani pẹlu awọn agbẹ.

Garba sọ pe ijọba ipinlẹ ti ṣetan lati gba ẹnikẹni pẹlu ẹran-ọsin wọn ni ipinlẹ naa.

Ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ darandaran jadejado orilẹede yi, Miyetti Allah Cattle Breeders Association of Nigeria ti ipinlẹ Kano sọ fun BBC pe awọn Fulani ni ipinlẹ naa n gbadun ọfẹ ati awọn ipese fun awọn ẹran wọn. Eyi ni idi ti ko fi si wahala laarin awọn ati awọn olubagbe ni agbegbe wọn.