Oluwo: Ọọni ran awọn eniyan lati yọmilẹnu

Ọọni ti Ilẹ Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi, Ojaja Keji Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Oluwo: 'Ọọni ran awọn eniyan lati yọmilẹnu'

Ija ti o wa laarin Ọọni ti Ilẹ Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi, Ojaja Keji ati Oluwo ti Iwo, Oba Abdurasheed Akanbi ti peleke si, lati igba ti wọn ti se'pade awọn Ọba ni Port Harcourt, ni'pinlẹ Rivers.

Oluwo wi pe awọn alaabo Ọọni lo tipa-ti-ikuku pẹlu ohun, eleyi ti Ọọni sọ wipe irọ patapata gbaa ni.

Oluwo wipe olori awọn ẹsọ alaabo Ọọni, t'orukọ rẹ njẹ Kọlawọle fa ohun kuro lọna ki Ọọni le e kọja, eleyi ti o fẹsun kan Ọọni wipe ohun ni o ran awọn ẹsọ alabo rẹ lati ti ohun kuro lọna.

Ninu ọrọ rẹ, oluranlọwọ fun Ọọni lori ọrọ iroyin, Moses Olafare sọ wi pe irọ patapata gbaa ni Oluwo pa mọ Ọọni ati wipe ogunlọgọ awọn oniroyin ati awọn ayaworan to wa nibi ipade naa yoo ti fi fọnran naa han gbangba to ba jẹ wipe iru isẹlẹ bẹẹ waye.