Ajọ eleto aabo pa afunrasi afipajinigbe ni'pinlẹ Ogun

Aajo SARS ti ijọba apapọ Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Minisita feto ẹkọ tẹlẹri, Iyabo Anisulowo lo ọsẹ kan ni ihamọ awọn agbenipa naa n'ipinlẹ Ogun

Aajo SARS ti ijọba apapọ ti pa afurasi ọmọ ẹgbẹ afipajinigbe kan, ti wọn n s'ọsẹ ni agbegbe Ilaro ni ijọba ibilẹ guusu Yewa ni ipinlẹ Ogun, ajọ ọlọpa ti sọ eyi di mimọ.

Agbenusọ fun ajo ọlọpa ni ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi nigba to n sọrọ lori isẹlẹ naa, wipe awọn ẹgbẹ ajinigbe naa ti ji ọkunrin kan, Saani Nasarawa gbe, ti wọn so o mọ igi fun ọjọ meje, nigba ti wọn duro de awọn ẹbi rẹ lati san owo idasilẹ

Oyeyẹmi wi pe ọkunrin ti wọn jigbe naa tu ara rẹ silẹ, ti o si na papa bo'ra nigba ti awọn ti o jii gbe n sun. Lẹyin eyi ni ọkunrin naa ba gba ile-isẹ awọn SARS ni Abeokuta lọ, lati lọ sọ gbogbo bi isẹlẹ naa se ri.

O fikun ọrọ rẹ wipe, ajọ SARS ko fa ọrọ gun rara, nibi adari wọn se lewaju iko to lọ koju awọn agbenipa ọhun, nibi ti wọn lugọ si.

Agbẹnusọ ajọ ọlọpaa naa sọ wipe ijakadi laarin awọn agbenipa naa ati ajọ SARS ja si iku ọkan lara wọn, ti awọn meje miran si farapa yẹlẹyẹlẹ nigba ti wọn na papa bo'ra. Ajọ SARS naa ri ibọn AK47 ti o ni ọta ibọn marundinlogun ninu.

Oyeyẹmi fi kun un wi pe, kọmisọna fun ajọ ọlọpa ni ipinlẹ naa, Ahmed Iliyasu wa parọwa si awọn ara ilu, ile-iwosan tijọba ati tibilẹ lati tete fi to awọn ọlọpaa leti, ti wọn ba ri ẹnikẹni to yọju sile iwosan pẹlu ọgbẹ ọta ibọn.

Related Topics