Yinyin ni Moscow: Awọn aworan to f'akọyọ

O le ni igi 2000 ti yinyin to lami laaka naa wo lulẹ ni olu ilu Russia:

Yinyin bo musiomu ti won fi awon ohun adayeba si ni Moscow - 4/2/2018 Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Moscow ti ri yinyin to pọju lọ lọjọ kan, lati igbati wọn ti bẹrẹ kika rẹ
Awon eniyan n wu oko ayokele won jade labe yinyin ni Moscow - 4-2-2018 Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Kosi ọkọ akero, ọkọ ayọkẹlẹ kan-an kan lo wa loju popo, sugbọn ọkọ oju'rin n sisẹ ni aja ilẹ
Awon eniyan rin ri ni Red Square, legbe St Basil Cathedral ni Moscow - 5-2-2018 Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Idaji yinyin ti wọn ri losu kan lo jabọ lọjọ abamẹta nikan soso - mejidinlogoji sentimita (iwọn marundinlogun)
Agbalagba okunrin kan n ko yinyin kuro niwaju ile re ni Moscow - 5-2-2018 Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Akọroyin BBC ni Moscow sọ pe awọn eniyan n bẹru ki wọn ma ha s'inu ile wọn ati ile-isẹ wọn
Omokunrin kan sere ninu yinyin ni Khimki, Moscow - 4-2-2018 Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Lọjọ isinmi, yinyin naa wo awọn igi, ti o si ba inọ mọnamọna jẹ ati wipe ọkọ oju ofurufu ko sisẹ lọjọ naa. Loni, ile iwe wa ni titi pa
awon eniyan n kopa ninu ere yinyin "skiing" Khimki, Moscow - 4-2-2018 Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Awọn miran naa n gbadun ara wọn ninu yinyin - ẹgbẹgbẹrun ko'pa ninu ere idije "skiing" lawọn igberiko ilu
Arakunrin kan n po tii ibile fun awon eniyan ni agbegbe Khimki, Moscow - 4-2-2018 Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Awọn akọsẹmọsẹ ati alaidasaka naa kopa ninu ere ije yinyin ti wọn n pe ni "Ski-Track of Moscow". Nibiyi, awọn eniyan n mu tii lati koju otutu
Aja kan sun lori yinyin to ga gogoro ni Moscow - 3-2-2018 Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Eniyan kan ti ku ninu oju ojo tori kurukuru ti ijọba sọ wipe o seese ko tesiwaju.

Aworan yi wa lati ile-isẹ iroyin: AFP, EPA ati Reuters.