IBB: Lootọ ni mo ni ki awọn ọmọ Naijiria yọ Buhari n'ipo

Ibrahim Babangida Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán IBB ni Naijiria si n wa adari to ba igba mu nibi ti aye laju de ni 2018

Aarẹ ologun nigba kan ri, Ibrahim Babangida ti fesi lori awuyewuye to suyọ lori atẹjade to fi sita, ninu eyi to ti sọ pe ki aarẹ Muhammadu Buhari o maa dije dupo lọdun 2019.

Ninu atẹjade naa ni Babangida ti sọ fun awọn ọmọ Naijiria lati ni suuru fun Buhari titi ti saa rẹ yoo fi wa s'opin ldun 2019.

O tun ṣatẹnumọ rẹ pe o se pataki ki awọn olori tuntun o jẹyọ.

Ṣugbọn laipẹ to fi atẹjade naa ti agbẹnusọ rẹ, Kassim Afegbua bu'wọlu lorukọ rẹ ni atẹjade mi i jade lati tako o.

Atẹjade tuntun naa ṣẹ kanlẹ lori awọn ọrọ to se koko ninu atẹjade akọkọ, tohun si ka wipe "IBB ni anfaani ibaraẹnisọrọ pẹlu awọn to wa nipo asẹ."

IBB ni atẹjade akọkọ ṣi duro, ati wipe oun o mọ nkankan nipa atẹjade keji.

"O ni oun fi atẹjade akọkọ sita lati se iwuri fun awọn oludije tuntun to fẹ dupo oselu, kiise lati fi ẹtọ ti aarẹ Buhari duun gẹgẹ bi oludibo taki oludije ni ọdun 2019."

Iroyin naa ti iwe iroyin Thisday fi sita loju itakun agbaye rẹ lọjọ aje ti wa fi idi rẹ mulẹ pe IBB o yi nkankan pada ninu atẹjade to kọkọ fi sita, sugbọn to jẹ wipe awọn to sunmọ lo fi ikeji sita pẹlu ontẹ rẹ.

Babangida lo yọ Ọgagun Mohammadu Buhari kuro nipo nigba ti o fi kọkọ jẹ aarẹ Naijiria ninu igbesẹ iditẹ gbajọba oni wọọrọwọ ti o waye ninu osu kẹjọ, ọdun 1985.