Metuh yọju sileẹjọ lori ibusun alaisan lori owo ipolongo PDP

Ipolongo ibo ẹgbẹ PDP Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Olisah Metuh n jẹjọ nitori owo ipolongo ibo to gba lọwọ PDP

Ileejọ giga ijọba apapọ to wa nilu Abuja ti sun igbẹjọ agbẹnusọ tẹlẹ fẹgbẹ oselu alaburada, PDP, Olisa Metuh siwaju pẹlu ọjọ pipẹ nitori ojojo to n se ogun rẹ, ti ara rẹ ko si le.

Ni kete ti adajọ Okon Abang to n gbọ ẹjọ naa foju kan Ọgbẹni Metuh lori ibusun alaisan ti wọn fi gbe wa lati ile iwosan lo ba kaanu rẹ, to si sun igbẹjọ naa siwaju.

Agbẹjọro fun Olisa Metuh, Agba amofin Onyeachi Ikpeazu lo kọkọ bẹ ileẹjọ pe ko sun igbẹjọ naa siwaju lasiko tigbẹjọ naa waye losu kinni ọdun yi.

Olisa Metuh yi si lo ti gbe iwe to gba latọdọ dokita to n tọju rẹ kalẹ fun ileẹjọ wipe ara oun ko da.

Igun Olupẹjọ ri iwe dokita Metuh bii ọ̀na lati sa lọ

Nigba to n fesi lori iwe yi, agbẹjọro fun igun olupẹjọ, Sylvanus Tahir, rọ ileẹjọ lati wọgile oniduro Metuh ti wọn gba, ko si ri aiyọju Metuh sile ẹjs gẹgẹ bii ete lati sa lọ.

Ninu idajọ rẹ, Ọgbẹni Abang fi idaniloju han pe iwe ti dokita fọwọsi pe ara Metuh ko ya yi to, lati gba ẹbẹ.

Amọ sa, Adajọ Abang ni ko si ẹri kankan lati fi idi rẹ mulẹ pe iwe ọhun jẹ ojulowo lati ọdọ dokita kankan.

Ọpọlọpọ eeyan si lo ti n sọrọ Metuh yi lori awọ̀n oju opo ayelujara: