Boko Haram:Ageku ejo rẹ si n soro bii agbọn

Awọ̀n ọmọ ikọ Boko Haram Image copyright BBC/Boko Haram
Àkọlé àwòrán Awọn Adunkoko mọni Boko Haram sefilọlẹ idunkuku laja wọn lọdun 2009

Lọpọ igba ni aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari maa n tẹnumọ pe wọn ti fi ẹyin ikọ adunkoko mọni Boko Haram janlẹ, sugbọn atupalẹ alaye nipa ikọlu Boko Haram si fihan pe ageku rẹ si n soro bii agbọn.

Iwadi ti ikọ atọpinpin BBC se fihan pe ikọ adunkoko mọni naa ti ran eeyan to le ni ẹẹdẹgbẹwa sọrun lọdun 2017 to kọja, eyi to pọ pupọ ju iye eeyan to gbẹmi wọn lọdun 2016 lọ.

Ni gbogbo ọdun 2017 ni ikọ Boko Haram fi n soro bii agbọn, to si n se ikọlu rẹ lemọlemọ laarin ọdun naa, eyi to n tako ikede aarẹ Buhari pe oun ti hu ikọ adunkoko mọni naa ti gbongbo-ti -gbongbo.

A ti ya iye Ikọlu Boko Haram yi sori aworan, irufẹ ikọlu ti Boko Haram nse ni ipele kọọkan, awọn adugbo ti wọn dojuks ati osu ti wọn se ikọlu, to tii pa eeyan julọ.

Awọn wo gan la n pe ni Boko Haram?

Ikọ adunkoko mọni ni Boko Haram, to si kọlu ijọba orilẹede Naijiria lọdun 2009 pẹlu erongba lati se agbekalẹ isejọba ẹlẹsin Islam lagbegbe iwọ oorun Afrika.

Ikọ naa, to dojukọ ẹkun ila oorun ariwa orilẹede Naijiria, lo ti ran eeyan bii ọkẹ kan (20,000) sọrun ọsangangan, to si tun ti sọ awọn eeyan bii miliọnu meji di alaini ile lori.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ilu Maiduguri lorilẹede Nigeria ni ibudo afojusun Boko Haram julọ

Boko Haram, ti Abubakar Shekau n dari rẹ, lo ti jẹjẹ atilẹyin rẹ fun ikọ tamọ ntiye ISIS losu kẹta ọdun 2015. Amọ nigba to di osu kẹjọ ọdun 2016, ni ikọ Boko Haram fọ si wẹwẹ, lẹyin ti ikọ IS kede pe wọn ti rọ Shekau loye.

Ọna taa fi se akojọpọ onka ikọlu Boko Haram.

Boko Haram jẹ ọkan lara awọn ikọ adunkoko mọni lagbaye to soro lati loye ohun ti wọn duro fun.

Lọna ati mọ bi ikọ naa se n se ikọlu rẹ, ni ikọ atọpinpin BBC se se akojọpọ awọn iroyin tawọn ileesẹ iroyin labẹle ati loke okun gbe sita nipa ikọlu Boko Haram lọdun 2016 ati 2017, pẹlu alaye nipa ikọọkan ikọlu ti wọn se.

Esi iwadi yi ko si gbọdọ fi sibikan lainaani pe o loju gbedeke kiko iroyin taa lee ko jọ nipa itankalẹ ẹsin Islam lẹkun iwọ oorun Afrika.

Akọroyin ileesẹ BBC to dojukọ orilẹede Naijiria, Andrew Walker, sọ fun ikọ atọpinpin BBC pe aibaradọgba lori bawọn ileesẹ iroyin labẹle se nkọ iroyin nipa ikọlu Boko Haram ati bi ikọ naa se n si kiri tumọ si pe ko lee seese lati se akojọpọ ẹkunrẹrẹ ikọlu Boko Haram yi lọna to pegede julọ.

Sugbọn pẹlu igbesẹ sise akojọpọ iroyin lati ileesẹ iroyin labẹle toto mejidinlaadọta, ti wọn kọ ni ede oyinbo, faranse, larubawa,atawọn ede mii to wa lẹkun iwọ oorun Afrika bii Kanuri, Hausa, ati Zarma, iwadi yi se afihan bi ọwọja ikọ Boko Haram ti mulẹ ninu ikọlu asekupani ti wọn nse ni agbegbe kọọkan.

Afikun nba ikọlu wọn sugbọn ibudo afojusun wọn ko yatọ.

Iroyin ni, apapọ ikọlu ti Boko Haram se jẹ aadọjọ (150) lọdun 2017, eyi si fihan pe ọwọ ikọ adunkoko mọni naa mulẹ pupọ lọdun 2017 ju tọdun 2016 lọ, nitori ikọlu mẹtadinlaadoje (127) lo se lọdun 2016.

Ni ọdun mejeeji yi, osu kinni ọdun ni ikọlu Boko Haram peleke julọ, ti ọwọja wọn si rinlẹ pupọ eyiun lẹyin ti aarẹ Muhammadu Buhari ti ni oun ti ri opin ikọ naa.

Àkọlé àwòrán Bi ikọ Boko Haram se n se ikọlu rẹ losoosu

Awọn ibudo ti Boko Haram n kọlu ko yatọ lati ọdun meji sẹyin.

Orilẹede Naijiria si lo faragba ọpọ ikọlu naa julọ lọdun 2016 ati 2017, ti ipinlẹ Borno si jẹ ilu abinibi awọn adunkoko mọni ọhun, ti wọn n dojukọ julọ.

Bakanaa ni ikọ Boko Haram fidi rẹ mulẹ pe oun lee tun gba ilẹ kan si lọdun 2017 pẹlu bo se tun kọlu ẹknu ariwa orilẹede Cameroon, agbegbe Niger Diffa ati Lake Chad, ti gbogbo wọn wa leti aala ilẹ ila oorun ariwa Naijiria.

Aworan yi se afihan awọn ibudo ti Boko Haram yan mu lati kọlu lọdun 2016, amọ iyatọ diẹdiẹ wa laarin ọdun meejeeji, ti orilẹede Naijiria si ni iriri ikọlu to pọ julọ lọdun 2017, ti orilẹede Niger si ni ikọlu Boko Haram to kere julọ lọdun naa.

Àkọlé àwòrán Aworan agbegbe ti Boko Haram kọ̀lu julọ̀ lọ̀dun 2016
Àkọlé àwòrán Awọn agbegbe ti Boko Haram kọlu Lọdun 2017

Ọna ti Boko Haram maa ngba se ikọlu rẹ.

Iroyin ni, ikọlu aadọrun (90) ni awọn gende agbebọn se nigbati ikọlu awọn aso ado iku mọra jẹ mọkandinlọgọta (59).

Orilẹede Naijiria naa si ni ori ikọlu wọnyi ta julọ, ti ikọlu Boko Haram to buru julọ si jẹ tawọn agbebọn.

Ni aala ilẹ Naijiria si Cameroon, ikọ naa nsamulo ilana to yatọ, ti wọn si nlo awọn aso ado iku mọra ju awọn agbebọn lọ.

Bakanaa ni wọn lo ilana yi lawọn orilẹede mejeeji lọdun 2016.

Àkọlé àwòrán Ikọlu Boko Haram lọdun 2016
Àkọlé àwòrán Ikọlu Boko haram lọdun 2017

Aworan yi lo n se afihan akọọlẹ iye ikọlu aso ado iku mọra to waye.

Lorilẹede Naijiria, ikọ Boko Haram se afikun ikọlu aso ado iku mọra rẹ lati mọkandinlogun (19) lọdun 2016 si mejidinlọgbọn (38) lọdun 2017, ti orilẹede Cameroon naa si foju wina ikọlu naa.

Afikun nba iye eeyan to nku, amọ ibudo afojusun wọn ko yatọ.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ọpọ igba ni ileesẹ ologun ilẹ wa ti kede pe oun ti ri ẹyin ikọ Boko Haram

O kere tan, eeyan bii ọtalelẹgbẹwa o le meje (967) ni ikọ Boko Haram ti ran sọrun lọdun 2017, eyi to kọja ikọlu okoolelẹgbẹwa o din mẹwa to waye lọdun 2016 ti iroyin gbe jade.

Ilu Maiduguri si ni wọn foju sun julọ, eyi to mu ki iye eeyan toku nibẹ pọ pupọ. Idi si ree ti adinku fi ba iye eeyan to wa nibẹ si miliọnu meji lati ọdun diẹ sẹyin, tawọn eeyan si n sa lọ sagbegbe igberiko.

Related Topics