Akẹkọ kan ku,ileẹkọ jona ninu ija akẹkọ fasiti Modibbo

Abawọle ileẹkọ fasiti Modibbo Adama Image copyright Modibbo Adama University website
Àkọlé àwòrán Rogbodiyan ija ẹsin nileẹkọ naa se akoba fun idanwo asejade fawọn akẹkọ

Ọrọ ti bẹyin yọ lori rogbodiyan to bẹ silẹ laarin awọn akẹkọ ileẹkọ fasiti imọ ẹrọ Modibbo Adama, to wa nilu Yola nitori awọn alasẹ ileẹkọ naa ti sọ agadagodo sẹnu ọna ileẹkọ ọhun.

Atejade kan ti akọwe agba ileẹkọ naa, Alhaji Ibrahim Ribadu fisita ni ija ẹsin to bẹ silẹ laarin awọn akẹkọ Kristiẹni ati Musulumi lo bi aawọ naa, eyi to sokunfa bi wọn se pasẹ fawọn akẹkọ naa lati gba ọna ile koowa wọn lọ.

Nigba to n ba ikọ iroyin BBC sọrọ, ọkan ninu awọn akẹkọ ileẹkọ naa, to fi orukọ bo ara rẹ ni asiri, fidi rẹ mulẹ pe ọrọ kan tawọn akẹkọ kan n fi ransẹ loju opo ikansiraẹni instagram eyi tawọn akẹkọ musulumi ri bi eyi to n tabuku Anọbi Muhammed lo sokunfa aawọ naa.

Awọn akẹkọ ko lee joko se idanwo mọ lọsẹ to n bọ.

O ni, ọrọ yi ti n ja rain-rain nilẹ ki eto idibo sinu ẹgbẹ awọn akẹkọ to waye. Bi awọn akọkọ Kristiẹni si se ko ọpọ ipo kanka-kanka ninu idibo naa lo bi awọn akẹkọ musulumi ninu, ti wọn si jọ tako ara wọn.

Iroyin naa ni, isẹlẹ naa buru de bi pe o mu ẹmi akẹkọ kan lọ, ti wọn si tun sọ ina sinu gbọngan ikẹkọ nla kan atawọn ibudo mii ninu ọgba ile ẹkọ ọhun.

Akẹkọ naa ni asẹ 'Ẹ lọ gbele yin naa', ko yọ akẹkọ kankan silẹ, to fi mọ awọn akẹkọ to fẹ kẹkọ jade, bẹẹ lo tun sediwọ fun idanwo ti wọn fẹ bẹrẹ lọsẹ to n bọ.

Ileesẹ iroyin Sahara reporters naa ti iroyin sita nipa isẹlẹ yi loju opo ikansira ẹni Facebook rẹ.