Kenya gbona lori ikọlu awọn ọlọọpaati oluwọde

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Ile isẹ amohunmaworan NTV,KTN ati Citizen TV wa lara awọn ile isẹ ti ijoba ko lati si

Awọn olopaa nilu Kenya ti yin afẹfẹ tajutaju lu awọn to'n fi ehọnu han pẹ ki ijoba si awọn ile isẹ amohunmaworan ti wọn ti pa lati ọse to koja.

Awọn ile isẹ naa lodi si asẹ ijoba pẹ ki wọn ma se afihan iburasipo olori alatako, Raila Odinga.

Raila Odinga fidiremi ninu idibo ọdun to kọja eleyi ti Uhuru Kenyatta jawe olu bori sugbọn o kọ lati gba abajade ẹsi ibo naa.

Ijọba funrare kọ lati tele asẹ ile ẹjọ to ni ki o si awọn ile ise iroyin to tipa pada.

Awọn olosẹẹlu alatako meji ni wọn mu pẹ wọn kopa ninu ayẹyẹ iburasipo naa.