Atunto ijoba ko le dẹkun wahala Naijiria

Ọgagunfẹyinti Alani Akinrinade Image copyright Bosede Sodiq
Àkọlé àwòrán Laisi aato isejọba lati isalẹ pẹpẹ, ohun to nse orilẹede Naijiria ko lee dawọ duro

Ilana isejọba to wa lode ni orilẹede Naijiria bayi faye gba were lati de ipo.

Ọgagun agba ileesẹ ọmọogun oriilẹ lorilẹede Naijiria nigbakanri, Alani Akinrinade lo sọ ọrọ yii nilu Osogbo.

Ọgagunfẹyinti Alani Akinrinade salaye wi pe pẹlu bi gbogbo awọn alẹnulọrọ lorilẹede Naijiria se npe fun aato isejọba ẹlẹkunjẹkun, federalism, ko daju pe eyi lee dẹkun wahala to n koju orilẹede Naijiria ni pato.

"Eto isejọba to wa nilẹ lorilẹede yii faaye gba gbigbe asiwere sori aga isejọba ti yoo si sọ gbogbo nkan bii ọgọsan miliọnu awọn ọmọ orilẹede yii to ku di asiwere pẹlu."

Ọgagunagba Akinrinade ni ọrọ orilẹede Naijiria ti di ti amukun, ẹru ẹ wọ to ni oke lẹ n wo, ẹ o wo isalẹ.

Image copyright Bose Sodiq
Àkọlé àwòrán Ipade lori ibagbepọ ẹya gbogbo lorilẹede Naijiria ko ye maa waye lati dẹkun wahala rẹ

O ni o di igba ti orilẹede Naijiria ba tun isejọba rẹ to de isalẹ pẹpẹ ki o to lee di wipe atunto isejọba ẹlẹkunjẹkun tawọn eeyan n pe fun kẹsẹjari.

"Bawo leeeyan se fẹ maa gbe ni awujọ ti olukaluku sa ti n fi ikilọ ati gbedeke lelẹ ni gbogbo igba. Se a o lee fi ọwọ ara wa sisẹ jẹ ni. Se gbogbo wa ni yoo maa lọ ta epo ni ẹkun aringbungbun gusu ilẹẹwa eleyi ti awọn babanla wa ko se."

"Ilẹ Yoruba gbọdọ jawọ ninu eto aragbe ti o nwaye lorilẹede Naijiria lọwọ ti kaluku n n gbe ẹnu si ohun to n ro jade ni ilẹ onilẹ."

O bu ẹnu atẹ lu ọrọ kan ti wọn ni minisita fun iwakusa ati ohun alumọni ilẹ lorilẹede Naijiria, Kayọde Fayẹmi sọ wipe, orilẹede Naijiria yoo sun kuro lori gbigbe ara le owo epo rọbi si owo iwakusa ati alumọni ilẹ.

Ọgagunfẹyinti Alani Akinrinade ni eyi yoo tun bẹrẹ si ni 'gbẹ koto kaakiri ileto ati abule lati lee tun maa da ija ati wahala ọrọ ayika silẹ.'