Femi Adesina ti wipe awọn alalumọkọrọyi n di ijọba Buhari lọwọ

Aarẹ Muhammadu Buhari Image copyright @NGRPresident
Àkọlé àwòrán Ọkan o jọkan ipe lo ti n jade fun Buhari lati mase dije lẹẹkeji lọdun 2019

Olubadamọran agba fun Aarẹ Buhari lori ọrọ iroyin, ọgbẹni Fẹmi Adesina ti salaye wipe awọn eeyan kan n gbiyanju lati di isejọba Muhammadu Buhari lọwọ isẹ rẹ.

Ninu fọnran fidio ọlọsọọsẹ to maa n fi sita eyi to fi sita lọjọ aje, ni Fẹmi Adesina ti sọ ọrọ yii.

Ọgbẹni Adesina ni, gbogbo isẹlẹ to n sẹlẹ lẹnu lọọlọọ yii, ko sẹyin ọna alumọkọrọyi tawọn eeyan kan fẹ gba lati pagidina isẹ takuntakun ti isejọba Aarẹ Muhammadu Buhari n se lawọn ẹka bii ipese ina ọba, irinna oju irin ati ọrọ aje lapapọ.

Image copyright AFP/Getty Images
Àkọlé àwòrán Oby Ezekwesili wa lara awọn to n lewaju ipolongo tako ijọba Buhari

" idi niyi tawọn eeyan kan fi faake kọri pe awọn yoo se idiwọ fun isejọba yii. Gbogbo awọn ikolu ati rogbodiyan wọnyi, gbogbo kaadi pupa, kaadi olomi buluu, kaadi alawọ rẹsurẹsu ti awọn eeyan kan n yọ sita bayii fun Buhari, ko ni isẹ meji to fẹ se ju lati pagidina isejọba yii lọ."

Ọrọ yii si lo n fesi si ipolongo ti asaaju ikọ to n polongo idapada awọn akẹkọbinrin Chibok, Obi Ezekwesili n se pẹlu bo se nkede opin si isejọba Buhari latipasẹ kaadi pupa to nna sita bayii.

Adesina, to ni gbogbo ọna ti owo ilu n gba jo si apo awọn eeyan kan ni ijọba Buhari ti di pa, sọ wi pe, owo to nwọle si asuwọn apapọ orilẹede yii lati ọdọ awọn lajọlajọ ati ileesẹ ijọba gbogbo ti gbe ẹnu soke sii.

Àkọlé àwòrán Lẹta ti Ọbasanjọ kọ si Buhari da ọpọ awuyewuye silẹ

O ni, aisi aaye fawọn eeyan wọnyii lati ko owo ilu si apo ara wọn, kun ara ohun to sokufa bi wọn se n dide lati pagidina eto isejọba pẹlu oniruru awawi ati ipolongo tako isejọba Buhari.

"Afojusun ijọba yii ni lati pese ina ọba ti agbara rẹ to ẹgbẹrun mẹwa mẹgawaati lọdun 2019. Ẹgbẹrun meji abọ megawatii ni agbara ina ọba ti Buhari ba nilẹ sugbọn o ti sun soke si ẹgbẹrun meje bayii, ti a si npin ẹgbẹrun marun ninu agbara ina yii fun araalu lọwọlọwọ."

Orisirisi ipe ati ipolongo lo ti n waye lọwọlọwọ bayii lati tako isejọba Buhari pẹlu oniruru ẹsun aikun oju osuwọn to latọdọ awọn araalu.

Eyi to se pataki laarin awọn ipe ati ipolongo yii ni lẹta ti aarẹ orilẹede Naijiria nigbakanri, Olusẹgun Ọbasanjọ kọ ati ipolongo oni kaadi pupa ti Oby Ezekwesili n lewaju rẹ.