Babangida kọ leta, l'ọlọọpa ba n wa agbẹnusọ

Agbẹnusọ fun Ibrahim Babangiga, Kassim Afegbua Image copyright Kassim Afegbua/Facebook
Àkọlé àwòrán IBB wipe ọfisi aarẹ Buhari ni iroyin wipe wọn yoo fi panpe ọba mu agbẹnusọ oun ti koko ru jade

Ajọ ọlọpa orilẹede Naijiria ti kede wipe awọn n wa Kassim Afegbua ti o jẹ agbẹnusọ fun aarẹ tẹlẹri, Ibrahim Babangiga lati fi panpẹ ọba mu.

Agbẹnusọ fun ajọ ọlọpa, Jimoh Moshood sọ wipe adari agba fun ajọ ọlọpa, Ibrahim Idris ti fun awọn lase lati fi panpẹ ọba mu ọgbẹni Afegbua fun gbolohun eke to fi lede, ati ibanijẹ ti o le da gbonmi si omi oto silẹ lawujọ.

Ninu ọrọ rẹ, Afegbua sọ wipe ohun yoo duro de agbejoro ohun lati fun ohun ni imọran lori ikede ajọ ọlọpa lati fi panpẹ ọba mu ohun.

Ti a ko ba gbagbe, agbẹnusọ fun Babangida naa fi atẹjade kan pẹlu ibuwọlu Babangida silẹ lori isejọba aarẹ Muhammadu Buhari, to si pe fun ki aarẹ Buhari o ma dije sipo aarẹ lọdun 2019. Sugbọn Babangida ni ohun ko ran agbẹnusọ nisẹ lati fi ọrọ naa lede.

Amọ, nirọlẹ ana, aarẹ tẹlẹri naa sọ wipe looto ni ohun bu'wọlu ọrọ ti agbẹnusọ ohun gbe jade. Ati wipe ọfisi aarẹ Buhari ni iroyin wipe wọn yoo fi panpe ọba mu agbẹnusọ Babangida naa ti koko ru jade.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí