ANC: Ipade pajawiri lori aarẹ Jacob Zuma yoo waye lọjọru

Aarẹ orilẹ-ede naa, Jacob Zuma

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Awọn alakoso igbimọ pe ipade pajawiri fun ọjọ aje lati jiroro lori Aarẹ Zuma

Ẹgbẹ oselu lorilẹede South Africa, ANC yoo sepade pajawiri lọjọru, lati jiroro lori ifiposilẹ aarẹ Jacob Zuma.

Ẹgbẹ naa fi eyi lede lẹyin ipade apaapọ wọn to waye ni olu ile-isẹ ẹgbẹ naa, ni Luthuti House, ni olu ilu orilẹede South-Africa, Johannesburg.

Oniroyin ile-isẹ AFP ti isẹlẹ naa soju rẹ, sọ wipe awọn ọmọ lẹyin aarẹ Zuma ati awọn alatako rẹ, fija pẹẹta nibi ipade naa, ti obinrin kan si farapa nibi ti wọn ti n fi igi naa.

Aarẹ Zuma naa ni wọn fi ẹsun kan lorisirisi wipe ohun hu'wa ibajẹ lawujọ, to si n lu owo ilu ni ponpo. Eleyi to jẹ ki awon egbe alatako o pe fun ifipo sile re lopo igba sehin.

Nibayi, awon egbe oselu re, The African National Congress so wipe awon adari egbe oselu naa yoo jiroro lori eto bi aare Zuma yoo se fipo adari sile fun igbakeji re, Cyril Ramaphosa to jawe olubori sipo adari ninu egbe oselu ANC.

Igbese yi waye saju oro ti aare yoo ba awon ara ilu so lodoodun lori bi nkan se n lo lorileede naa.

Egbe alase orileede South-Africa, National Executive Committe ni egbe to gaju lo ninu egbe oselu ANC, won si ni ase lati pe fun ikowe fipo sile aare Zacob Zuma.

Iroyin fi lede wipe opo eniyan ninu egbe oselu naa fe ki igbakeji aare ile naa o gori oye gege bi aare, sugbon awon alatileyin fun aare Jacob Zuma sowipe o pon dandan fun aare Jacob Zuma lati pari saa re gege bi aare, ki won to seto idibo gbogboogbo lodun to hun bo.