Kaadi idanimọ lọna abayọ siwa ijẹkujẹ - Onimọ feto ẹnawo

Aworan ile-ise EFCC Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán EFCC lawon ri eedegbeta(500) Billionu Naira gba pade lodun 2017

Onimọ kan nipa eto ẹnawo, Olusọla Gbadamosi ti rọ ijọba lati pese kaadi idanimọ ti yoo safihan iye owo ti awọn osise ati awọn oselu n gba lati gboogun tiwa jẹgudujẹra lawujọ.

Ọgbẹni Gbadamosi gbe imọran yi kalẹ nigba to n ba akọroyin BBC sọrọ lori ikede ajọ EFCC pe oun ri owo toto eedegbeta (500) billiọnu naira gba pada lọwọ awọn jẹgudujẹra to n lu owo ilu ni ponpo lọdun 2017.

Adele alaga fun ajọ EFCC, Ibrahim Magu, nigba to n ba ile igbimọ asoju-sofin sọrọ lori iye owo ti wọn ri gba pada ọhun sọ pe, awọn ri biliọnu mejilelọgbọn Naira ati Milliọnu marun dọla gba pada lọwọ Minista tẹlẹ fọrọ epo rọbi, Alison Madueke.

Wọn tun ri owo mii ni yara igbafẹ kan nilu Eko ati biliọnu metalegoji dọla mii ninu ile kan lagbegbe Ikoyi nilu Eko, pelu ọpọ owo miran bẹẹ, ti apapọ rẹ jẹ owo to le ni ẹẹdẹgbẹta billiọnu naira.

Ọgbẹni Gbadamosi wa parọwa si ijọba apapọ lati lo owo naa fun igbayegbadun awọn araalu ati wipe kaadi idanimo ti yoo ma sọ iye owo ti enikọọkan n gba, yoo foju awọn ti wọn n lu owo ilu ni ponpo sita, eyi to ti n fa ifasẹhin fun ọrọ ajẹ orilẹede Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOnimọ wipe kaadi idanimọ yoo ran ajọ EFCC lọwọ ati koju jẹkudujẹra