EPL: Watford lu Chelsea la'lubolẹ pẹlu amin ayo mẹrin

Ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ninu idije Premier League pẹlu Watford

Watford ti fa'gba han ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ninu idije Premier League pẹlu amin ayo mẹrin si ẹyọ kan soso.

Eyi jẹ asalẹ maleegbagbe fun akọnimọọgba fun ẹgbẹ agbabọọlu Watford, Javi Gracia ati akọnimọọgba fun ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea, Antoni Conte.

Ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea padanu ọkan lara awọn igi lẹyin ọgba rẹ, Tiemoue Bakayako lẹhin asesemase lẹẹkeji ti wọn si gba bọọlu fun wakati pẹlu awọn mẹwa.

Àkọlé àwòrán,

Watford b si ipo kọkanla lori tabili premier league

Gracia, ti o rọpo Marco Silva ni osu to kọja, sọ fun BBC Sport wipe: "O jẹ aseyọri ati iṣere nla fun awọn ẹgbẹ agbabọọlu Watford.

"A gbiyanju takun-takun ninu idije yii, pẹlu wipe lile ti wọn le Bakayoko jade jẹ ohun ti o se ikunọ fun ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea. Sugbọn, ẹgbẹ agbabọọlu Watford naa tara mọ idije yii lati bori nitoripe ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea jẹ ọkan ninu awọn ti o dara julọ nilẹ gẹẹsi".

Àkọlé àwòrán,

Conte gbodo tun iko Chelsea se ki won too koju West Brom

Lẹyin eyi, ẹgbẹ agbabọọlu Watford yoo lọ si West Ham ni ọjọ abamẹta nigba ti ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea yoo gbalejo ẹgbẹ agbabọọlu West Brom.