Kassim Afegbua yoo jọ'ju si agọ ọlọọpa lọjọru

Kassim Afegbua, agbẹnusọ ọgagun Babangida Image copyright Kassim Afegbua
Àkọlé àwòrán Wa koju awọn ọlọọpa o

Kassim Afegbua, agbẹnusọ fun aarẹ orilẹede Naijiria nigbakan ri, Ibrahim Babangida, ti awọn ọlọpa sọ pe awọn n wa ti kigbe pe oun ko sẹ ati wipe oun ko jẹbi aiṣedede kankan.

Ṣugbọn agbẹnusọ naa sọ pe oun yoo ju ara oun silẹ fun awọn ọlọọpa ni ọjọru, ati pe oun setan lati ja fun ẹtọ oun ni ile ẹjọ.

Ọgbẹni Afegbua se atẹjade ọrọ ni ọjọ aiku ti Ọgbẹni Babangida, ti o jẹ olori orilẹede tẹlẹ, lo lati ṣe bu ẹnu ẹtẹ lu eto isejọba Aare Muhammadu Buhari ninu eyi ti o fi gba awọn ọmọ Naijiria ni imọran lori ilọsiwaju eto oselu orilẹede yii.

Lẹhin wakati diẹ ti wọn gbe ọrọ yi jade, atẹjade miran jade lati tako ọrọ naa; ti o si da ruke-rudo silẹ.

Ni kiakia ni iroyin bẹẹrẹ wipe awọn ọlọpa n wa ọgbẹni Afegbua.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn amofin fun ọgbẹni Afegbua salaye pe o setan lati y'ọju si agọ ọlọpa ni ọjọru

Ogbeni Afegbua ti sọrọ ninu atẹjade kan ti awọn amofin rẹ gbe jade, wọn sọ pe Agegbua "jẹ akọsẹ-mọsẹ onise iroyin ti gbogbo eniyan mọ ati pe o tun jẹ Kọmisọna fun eto ọrọ nipinle Edo nigbakan; o ni ile ni ilu Abuja ati ilu Benin ṣugbọn agọ ọlọpa ko fi iwe ipe ransẹ sibi kankan lati pee si agọ wọn.

"Gẹgẹbi ọrọ ti o wa lati ile isẹ amofin Kayode Ajulo & Co. nilu Abuja, o sọ pe "Fun aiyọyemeji, awọn ilana ti a fi ṣe akọsilẹ ni o wa fun ikede ẹni ti eniyan ti awọn ọlọpa nwa, awọn ọlọpa gbọdọ tẹle awọn ilana yii."

"Nibayi, Onibara wa ti fun wa ni asẹ lati pe ile isẹ amohunmaworan NTA ati ọlọọpa sile ẹjọ lati sọ ohun ti wọn ri l'ọbẹ fi wa iru s'ọwọ.

Awọn amofin fun ọgbẹni Afegbua salaye pe o setan lati y'ọju si agọ ọlọpa ni ọjọru.