WHO: Ko s'anfaani ninu abẹ dida f'ọmọbinrin

Abẹ ti wọn maa nlo fun abẹ dida Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ijamba to pọ ni abẹ dida fawọn obinrin ti se nilẹ adulawọ

Ọjọ kẹfa, osu keji ni ayajọ ọjọ igbogun ti asa abẹ́ dida fun awọn ọmọbinrin lagbaye. Asa naa ni ọpọlọpọ ajafẹtọ awọn obinrin ti sapejuwe gẹgẹ bi igbesẹ titẹ ẹtọ awọn obinrin loju.

Ajọ WHO ni ''o le ni miliọnu mẹta awọn ọmọbinrin to wa ninu ewu ati lugbadi abẹ dida lọdọọdun."

Lọdun 2015, aarẹ Naijiria nigba kan, Goodluck Jonathan buwọlu ofin to de asa naa, ti awọn to tako asa naa si sapejuwe igbesẹ Jonathan gẹgẹ bi igbesẹ ilọsiwaju ni ilẹ Afirika nitori wipe Naijiria ni asa naa ti wọpọ ju.

Lori eyi, ọjọgbọn Modupe Ọnadẹkọ, to jẹ onimọ nipa eto ilera ati oludari ẹkaajọ to n gbogun ti awọn asa ti ko bojumu lagbaye ni Naijiria ninu ifọrọwanilẹnuwo to se pẹlu BBC Yoruba ni:

"Lootọ ni ofin yii wa sugbọn awọn ni eyi ko ti fi opin si asa yii ni Naijiria nitori wipe awọn ipinlẹ kan ko ti i buwọlu iru ofin yii ati wipe awọn agbofinro ko maa se isẹ wọn bi o se tọ."

"Ati wipe oru ni awn to n se fi n boju bayi."

Bakanna lo se alaye bi wọn se maa n se e :

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionModupe Onadeko lori asa abẹ dida fun ọmọbinrin

Ajọ ninu iwadi kan to se ni ida mejidinlọgbọn awọn obinrin Naijiria ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mẹẹdogun si mọkandinlaadọta lo ti lugbadi igbesẹ yii gẹgẹ bi ajọ. Ẹya Yoruba, ko ida mẹrinlelaadọta ataabọ ninu awọn to n kopa ninu asa naa ni Naijiria.

Asa yi loju awọn to n se jẹ nkan to se pataki ninu títọ́ ọmọbinrin, ati gẹgẹ bi ọna lati mura rẹ silẹ fun ipo agba ati igbeyawo.

Ara igbagbọ wọn tun ni pe yoo jẹ ki ọmọbinrin le pa ibale rẹ mọ ati wipe ko ni jẹ ki o le ni ibalopọ lode igbeyawo, ti yoo si jẹ ki o le jẹ olootọ si ọkọ rẹ ninu igbeyawo.

Awọn ewu to rọ mọ abẹ́ dídá.

Image copyright Getty Images
  • Ẹjẹ to maa n da lara wọn ti maa n pọju ti ọmọ si le gba ibẹ kuO maa n fa irora fun iru ọmọ bẹ ẹ
  • Kokoro aifojuri to fi mọ aarun HIV le e gba ibẹ wọ ara ọmọ nitori pe awọn to n se kii lo awọn irinsẹ ti wọn se lọjọ
  • O maa n fa inira fun obinrin lasiko to ba fẹ bimọ nitori wipe oju ara wọn yoo ti kere
  • Awọn ọkọ wọn kii gbadun ibalopọ pẹlu wọn, eyi si le da ile ru.
  • O le fa aisan ti oyinbo n pe ni ''Fesico Vaginal Fistula''.Igá ati ìtọ̀ yoo ma jade lati ibi kan na
  • Airọmọbi
  • Ipalara fun ile ọmọ obinrin.