Buhari: Ajeji ko nii gba isẹ saaju ọmọ Naijiria mọ

Aworan aarẹ Buhari lasiko toun tọwọ bọwe Image copyright @MBuhari
Àkọlé àwòrán Buhari ni ifojusun idasile isẹ lọpọ yanturu leka imọ ijinlẹ ati ẹrọ aye daade ni ẹkun iwọorun ile Afrika.

Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti buwọlu iwe asẹ kan lati bominrin ipese awọn ohun elo labẹnu fun idasile isẹ lọpọ lẹka imọ ijinlẹ ati ẹrọ aye daade ni ẹkun iwọ-oorun ile Afrika.

Bakana ni aarẹ Buhari se alaye wipe awọn ọmọ orilẹede yi logbudọ kọkọ jẹ anfani ilẹ baba wọn saaju awọn ajeji ti o wa lati ilẹ okeere.

Lẹyin osu diẹ ti aarẹ gun ori apẹrẹ ijọba ninu osu kaarun ọdun 2015, ile ifowopamọ agba lorilẹede yi dena kiko ọja wọle lati ilẹ okeere lojunna ati pakun ipese awọn ohun elo ti o jẹ tiwa n tiwa.

Lasiko ti o n sọrọ lori itọna twitter lọjọ aje, aarẹ orilẹede yi pasẹ fun gbogbo awọn eniyan to wa ni ipo asẹ lati woose fun awọn ile isẹ ti o je ti orilẹede Naijiria saaju awọn onile isẹ ti o wa lati ilẹ okeere ni ibamu pẹlu ofin ilẹ wa ọdun 2007 toun se akoso awọn dukiya ijọba.

Asẹ naa kesi ẹka ti o n risi ọrọ abẹnu lorilẹede yi lati dẹkun gbigbe awọn isẹ ti a le se nilẹ yi fun awọn ajeji ti o wa lati ile okeere.