Antonio Conte: Cahill ati Courtois gbe lẹyin akọnimọọgba Chelsea

Aworan Antonio Conte nibi ifọrọwanilẹnuwo kan
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea tijuwe ile fun ọpọlọpọ awọn akoni mongba to fidirẹmi

Balogun ikọ Chelsea, Gary Cahill ti gbe lẹyin Antonio Conte, gẹgẹ bose n n keesi awọn akẹgbẹ rẹ lati se agbeyẹwo iredi ti wọn fi fidi rẹmi sọwọ Watford pelu ami ayo mẹrin si odo.

Lẹyin ifidirẹmi meji otọọtọ ti o tẹ le ra wọn, Conte se alaye wipe oku sọwọ awọn alakoso ẹgbẹ agbabọọlu naa lati gbe igbesẹ ti o tọ bi isẹ rẹ ko ba kun oju osunwọn to.

Ẹgbẹ naa ti o n gbiyanju lati da aabo bo ife ẹyẹ ti wọn gba sẹyin ti wa ni ipo kẹrin ninu idije Premier League, pẹlu ami ayo mọkandinlogun lẹyin ikọ Manchester City.

Ninu alaye rẹ, Cahill se alaye wipe awọn agbabọọlu ikọ na lo se okunfa ifidirẹmi wọn nitoripe Conte ti sisẹ takuntakun.

Saaju Conte ni Conte mun ki ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea gba ife ẹyẹ lodun akọkọ ti o bẹrẹ isẹ, sugbọn o ti bẹrẹ sini koju awọn ọkanojọkan ipenija lati igba ti ikọ naa ti fidi rẹmi sọwọ ẹgbẹ agbabọọlu Burnley nibẹrẹ idije toun lọ lọwọ.