Saraki bẹrẹ awijare nileẹjọ CCB

Sẹnatọ Bukọla Saraki Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Sẹnatọ Bukọla Saraki pada sileẹjọ CCB lẹyin ti ileẹjọ kotẹmilọrun sọpe o lẹjọ lati jẹ

Ọmọ igbimọ tẹlẹ ninu ajọ to nrisi ihuwasi awọn osisẹ ọba atawọn to dipo asẹ mu, CCT, Ọmọwe Ademọla Adebọ ti yọju igbimọ eleto idajọ to n gbọ ẹsun iwa asemase awọn eeyan to dipo oselu mu ati osisẹ ọba, CCB.

Ọmọwe Adebọ wa jẹri lorukọ aarẹ ile asofin agba, Dokita Bukọla Saraki, ẹni to n jẹjọ lọwọ lori ẹsun mẹta ti wọn fi kan-an pe o parọ nidi kikede dukia rẹ.

Ọjọ isẹgun ni igbẹjọ bẹrẹ pada lori awọn ẹsun ti wọn fi kan Saraki lẹyin ti ileẹjọ kotẹmilọrun nilu Abuja da mẹta ninu awọn ọmọ igbimọ ajọ CCT naa pada ninu awọn mejidinlogun ti alaga igbimọ CCT, Danladi Umar yọ nipo.

Saraki kẹdun pẹlu alaga CCT

Lẹyin idajọ ileẹjọ kotẹmilọrun yi, ni ajọ CCT fi ikede sita pe kawọn igun ti igbẹjọ Saraki kan, bẹrẹ sini yọju sileẹjọ lori ẹsun oni koko mẹta, ti wọn fi kan Sẹnatọ Saraki ọhun.

Nibi igbẹjọ naa si ni igun agbẹjọro Saraki ti kesi Ọmọwe Adebọ lati wa jẹ ẹlẹri akọkọ wọn.

Nigba to ndahun ibeere latẹnu ọkan lara agbẹjọro Saraki, agba amofin Paul Usoro (SAN), Ọmọwe Adebọ ni osu kẹrin ọdun 2010 ni wọn yan oun sinu igbimọ oludari CCT amọ ti oun bẹrẹ isẹ ni ọgbọnjọ osu kẹrin ọdun 2010

Sẹnatọ Bukọla Saraki gan sọrọ nipa igbẹjọ rẹ loju opo Twitter rẹ.