Babalawo sọ pe ẹtan ni imulẹ fun Asẹwo
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Agba Awo kan ni imulẹ fun awọn olowo nabi naa ko muna d'oko

Agba Awo nilẹ Ibadan, Idowu Olukunle ti salaye pe ẹtan lasan ni bawọn onigbọwọ awọn olowo nabi to n ko awọn asẹwo lọ soke okun, se maa n dun mahuru mọ wọn .

O ni, wọn kan n gbin ibẹru lasan sinu ọkan awọn asẹwo naa ni, kii se pe ibẹru ti wọn dijọ se, lee pa wọn lara.

Baba Awo Olukunle wa parọwa sawọn olowo nabi ti wọ̀n ba fẹ gbe lọ soke okun ati gbogbo ọmọ Naijiria lapapọ lati mase lọwọ ninu sise ibura pẹlu ẹnikẹni.