NHIS: Aarẹ Buhari da Usman Yusuf pada s'ipo gẹgẹ bi akowe eto ilera

Image copyright nhis.gov.ng
Àkọlé àwòrán Minisita foro ilera ni Naijiria yọ Usman Yusuf

Aarẹ Muhammadu Buhari ti da akọwe ajọ to n risi eto adoju-tofo lẹka eto ilera Naijiria (National Health Insurance Scheme), Usman Yusuf pada sẹnu iṣẹ lẹyin ti Minista fọrọ ilera yọ ọ kuro nipo lori ẹṣun jẹgudujẹra.

Ki Adewọle o to yọ akọwe Yusuf nipo, igbimọ t'o ṣewadi lori aṣemaṣe nile isẹ eto ilera, sọ wipe ọgbẹni Yusuf lu owo ilu ni ponpo, to si ji owo awọn ar'ilu.

Amọ, iroyin fi lede wipe aarẹ Buhari ko ro ti ẹsun ti wọn fi kan an, ki o to o da akọwe ajọ naa pada s'ẹnu iṣẹ.

Gẹgẹ bi iroyin ṣe fi idi rẹ mulẹ, lẹta ti wọn fi pe e pada sẹnu iṣẹ ni wọn fi ṣ'ọwọ si Minisita fọrọ ilera lọjọ isẹgun, ti Adewọle si sọ fun awọn oniroyin wipe, lootọ ni ohun gba lẹta lati da ọgbẹni Yusuf pada s'ẹnu iṣẹ.

Minisita fọrọ ilera ni Naijiria fikun un wipe lẹta naa rọ oun lati sisẹ pẹlu ifọwọsowọpọ pẹlu ọgbẹni Yusuf ti o ba ti pada s'ẹnu iṣẹ.