Ajọ JAMB sun opin ọjọ iforukosilẹ idanwo s'iwaju

Awọn akẹkọ idanwo aṣewọle s'ile ẹkọ giga, JAMB Image copyright @JAMB
Àkọlé àwòrán Ajọ JAMB sun opin ọjọ iforukosilẹ idanwo s'iwaju

Ajọ to n risi eto idanwo aṣewọle s'ile ẹkọ giga, JAMB ti kede isunsiwaju opin ọjọ iforukọsilẹ fun idanwo ti ọdun yii si ọjọ kọkanla, osu keji, ọdun yii.

Agbẹnusọ fun ajọ naa, Fabian Benjamin sọrọ yi fun awọn akọroyin ninu atẹjade ti o tẹ awọn oniroyin lọwọ.

Ninu ọrọ naa, JAMB wipe nitoripe awọn jẹ ojulowo ajọ t'o fẹran ilọsiwaju awọn akẹkọ ni awọn ṣe fi aaye s'ilẹ fun awọn ti ko ba tii f'orukọ s'ilẹ fun idanwo naa lati se eyi laarin ọsẹ meji.

Amọ, ajọ naa sọ wipe isunsiwaju lọjọ iwaju le e mu ijiya kan tabi omiran lọwọ, fun awọn akẹkọ ti ko ba f'orukọ silẹ lasiko ti o yẹ.

Ninu atẹjade naa ni ajọ JAMB ti fi lede wipe idanwo naa ṣeeṣe ki o waye lọjọ kẹsan si ọjọ kẹtadinlogun, osu kẹta, ọdun 2018.