Waec f'ofin de ile'we mẹtadinlaadọta ni Kogi

awọn akẹkọ ile iwe girama nilu eko Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Idanwo Waec jẹ idanwo asekagba lọ si ile iwe giga

Ajọ t'o n risi idanwo lapa iwọ-oorun Afrika (Waec) ti fi ofin de ile ẹkọ Girama mẹtadinlaadọta ni ipinlẹ Kogi, ti wọn f'ẹsun sise agbatẹru magomago lasiko idanwo ajọ naa kan.

Kọmisọna f'ọrọ eto ẹkọ ni'pinlẹ Kogi, Rosemary Osikoya ti o fi ọrọ naa lede nigba ti wọn n se ipade awọn oniroyin n'ilu Lokoja lọjọ iṣẹgun, sọ wi pe ajọ WAEC fi lẹta naa ranṣẹ si ile-iṣẹ ijọba ipinlẹ naa.

Osikoya wipe awọn ile-iwe Girama ti ijọba ati ti aladani wa ninu awọn ile-iwe ti wọn f'ofin de naa kaariri ipinlẹ Kogi.

Ninu ọrọ rẹ, o wipe mẹtala ninu awọn ile iwe Girama naa ni aṣemaṣe wọpọ si, ti o si fikun un wipe ijọba ipinlẹ naa yoo fikun ijiya awọn ile ẹkọ bẹẹ.

Kọmisọna fun eto ẹkọ wipe, awọn n ṣiṣẹ pọ pẹlu Ajọ awọn Olukọ Lapapọ (National Teachers Institute) lati bawọn kọ ọgọrun olukọ, pẹlu ireti wipe eleyi yoo mu ilọsiwaju ba eto ẹkọ ni ipinlẹ naa.

Àwọn ojú òpó ayélujára tí ó jọ èyí

BBC kò mọ̀ nípa àwọn nnkan tí ó wà nínú àwọn ojú òpó ayélujára ní ìta