2018 FIBA World Cup: Nigeria, Argentina, Australia wa papọ

Awọn ọmọbinrin Naijiria to n gbabọọlu alafọwọjus'apẹrẹ, D'Tigress Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán 2018 FIBA World Cup: Nigeria yoo koju Argentina

Awọn ọmọbinrin Naijiria to n gbabọọlu alafọwọjus'apẹrẹ, D'Tigress ni wọn ti pin si isọri keji, (Group B) pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Argentina, Turkey ati Australia to gbe'gba oroke lọdun 2006, ninu idije ife ẹyẹ agbaye fawọn obinrin ti yoo waye ni orilẹede Spain losu kẹsan ọdun yii.

Nibi ayẹyẹ kan lọjọ iṣẹgun, ni Teatro Leal, San Cristobel de la Laguna, wọn pin Korea, Greece, Canada ati France si isọri kini, nigbati orilẹede to n gbalejo wọn, Spain, Japan, Puerto Rico ati Belgium wa ni isọri kẹta, Group C.

Ifesewonse ti isori yoo waye ni papa isere, Tenerife Sports Pavilion Santiago Martin ni San Cristóbal de La Laguna ati Palacio Municipal de Deportes ni Santa Cruz, nigbati ifesewonse ti asekagba yoo waye ni papa isere, Tenerife Sports Pavilion Santiago Martin.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awon orileede tohun soju Afirika tun ni Senegal to wa Isori Kerin, Group D pelu Latvia, USA ati China

Awon orileede tohun soju Afirika tun ni Senegal to wa Isori Kerin, Group D pelu Latvia, USA ati China.

Akonimogba fun egbe agbaboolu alafowojusapere, Sam Vincent so wipe pinpin ti won pin awon pelu Argentina yoo ki awon igbaradi lopolopo fun ife agbaye naa.

Bee si ni, agbaboolu iwaju, Evelyn Akhator so wipe ohun ni igbagbo wipe awon yoo se daradara ju tateyinwa lo ati ti odun 2006 ti won ti fidi remi lasiko idije ifesewonse ti isori, ti won si se ipo kerinlelogun ninu idije naa.