Ile asofin fajuro si ọmọogun Cameroun to nwọ Naijiria laigbasẹ

Awọn ọmọogun Cameroun Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Wọn fẹsun kan awọn ọmọogun Cameroun pe wọn nwọ Naijiria lai gbasẹ́

Awọn asofin apapọ orilẹede Naijiria ti koro oju si bi awọn ọmọogun orilẹede Cameroun kan se tasẹ agẹrẹ wọ aala ilẹ Naijiria lawọn agbegbe kan.

Eyi lo si mu ki awọn asofin agba orilẹede Naijiria kesi minisita fun ọrọ aabo lati farahan niwaju igbimọ rẹ ko lee salaye lori isẹlẹ naa.

Lọjọ kẹẹdọgbọn osu kinni ọdun 2018 ni ọgọrin awọn ọmọogun orilẹede Cameroon tasẹ agẹrẹ wọ aala ilẹ Naijiria lẹkun Danare-Daddi/Danare-Bodom ni ibi ti wọn ti ji awọn eeyan marun gbe.

Image copyright AFP/Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọpọlọpọ awọn eeyan agbegbe guusu Cameroun lo ti wọ Naijiria nitori wahala abẹle to n sẹlẹ lorilẹede wọn

Igbesẹ yi si lawọn sẹnatọ ọhun ri gẹgẹbi iwa titapa si ofin orilẹede Naijira.

Bakanna lawọn asofin agba yi tun kesi ileesẹ ọmọogun Naijiria lati tubọ se alekun awọn ọmọogun ti yoo maa daabo bo aala ilẹ Naijiria ati awọn ẹnu ibode rẹ gbogbo.

ọkan-o-jọkan awọn asofin to sọrọ nibi ijoko ile lọjọru ni wọn koro oju si ohun to sẹlẹ yi.

Image copyright AFP/Getty Images
Àkọlé àwòrán Bi awọn eeyan se n wọ awọn ileto to wa ni aala Naijiria ati Cameroun se n pọ sii ni wahala abo pẹlu n yọju

Ninu ọrọ rẹ, Sẹnatọ Sam Egwu ni, o yẹ ki ile o bi minisita fun ọrọ abo nipa idi ti yoo fi la oju rẹ silẹ ti orilẹede miran yoo fi wọ orilẹede Naijiria, ti yoo si maa tẹẹ basubasu.

Ọrọ asepọ laarin orilẹede mejeeji yii ti n ni gbọnmisi-omi o too ninu lẹnu lọwọlọwọ yii, eyi ti ko si sẹyin wahala abẹle to n waye lorilẹede Cameroun nitori bi ẹkun guusu orilẹede naa se n beere fun ominira.

Isẹlẹ yi ti sọ eeyan bii ẹgbẹrun mẹwa ni guusu Cameroon di alarinkiri ati atipo lawọn ileto kaakiri ipinlẹ Cross rivers lorilẹede Naijiria.