Benue gbalejo aabo kogberegbe latọdọ ologun

Awọn ologun joko sori ilẹ Image copyright @HQNigerianArmy
Àkọlé àwòrán Awọn ologun ti kọkọ se eto abo kogberegbe Python dance ati Crocodile Smiles

Ileesẹ ọmọogun Naijiria yoo bẹrẹ eto aabo ko-gba-gbẹrẹ kan lawọn ipinlẹ bii Benue Taraba, Kogi, Nasarawa, Kaduna ati Niger lati lee wagbo dẹkun si gulegule isẹlẹ ijinigbe, ikọlu darandaran ati agbẹ olohun ọsin atawọn iwa ọdaran miran.

Wahala ijinigbe ati ikọlu oun ipaniyan laarin darandaran fulani ati awọn agbẹ olohun ọsin ti di tọrọ fọnkale lẹkun aringbungbun ariwa orilẹede Naijiria nibiti ọpọlọpọ ẹmi ti ku.

Oludari idanilẹkọ ati isẹ gbogbo nileesẹ ọmọogun orilẹede yi, Ọgagun David Ahmadu to sọrọ lorukọ olori ileesẹ ọmọogun oriilẹ, Tukur Buratai, ni, laarin ọjọ kẹẹdogun osu keji si ọjọ kọkanlelọgbọn osu kẹta ọdun 2018 ni eto abo kogberegbe naa yoo fi waye.

Igba akọkọ kọ ree ti ileesẹ ologun Naijiria yoo pese akanse aabo bi eyi

Gẹgẹbi ileesẹ ọmọogun oriilẹ ni Naijiria se sọ, orukọ apejẹ ti wọn fun eto abo kogberegbe naa ni ‘exercise Ayem Akpatuma‘, eyi to tumọ si ere ije ologbo ni ede awọn ẹya Tiv.

Laarin ọjọ mẹrinlelogoji ti eto aabo kogberegbe yii yoo fi waye, awọn ologun yoo maa kọlu ibuba awọn kọlọransi onisẹ ibi, ti wọn yoo si tun maa se eto ayẹwo oju popo lawọn ibi to yẹ kaakiri.

Saaju asiko yii, ileesẹ ologun Naijiria ti se irufẹ eto aabo kogberegbe yii bi Python dance I, II, III lẹkun aringbungbun guusu orilẹede yi ati Crocodile smile I, II ni ẹkun ila oorun guusu Naijiria.