Awọn asofin agba yoo sewadi ilẹkun baalu Dana to fo yọ

Senatọ Bukọla Saraki Image copyright @bukolasaraki
Àkọlé àwòrán Ile asofin agba orilẹede Naijiria ni asiko to fun amojuto to peye lẹka irinajo afẹfẹ

Iroyin ilẹkun baalu Dana to sa dede ja ni papakọ ofurufu nilu abuja lo n ja ranyinranyin, ti aarẹ ile asofin agba lorilẹede Naijiria, Sẹnatọ Bukọla Saraki si ti salaye pe ile asofin agba yoo se iwadi si isẹlẹ ọhun.

Saraki salaye ọrọ yi ninu ọrọ to fi sita lori ikanni ibanisọrọ tuwita rẹ pe awọn asofin agba lorilẹede Naijiria ko ni foju lasan wo isẹlẹ naa nitori kii se ohun to tọna ki ilẹkun baluu maa sadede fo yọ.

Aarẹ ile asofin agba wa ki awọn ero to wọ baalu naa, lasiko ti isẹlẹ ọhun waye ku akoyọ ewu.

O ni gbogbo awọn ileesẹ ọkọ ofurufu to wa lorilẹede Naijiria lo gbọdọ mọ wipe ọranyan ni aabo awọn ero to n wọ baalu wọn; bẹẹni amojuto to peye ni lati wa lori awọn baalu ti wọn nlo.

Ohun ti Sẹnatọ Bukọla Saraki sọ

"A dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ẹ gunlẹ layọ."

Aabo awọn ero ati itọju awọn baalu jẹ ọranyan fun gbogbo ileesẹ irinna ofurufu to n sisẹ lorilẹede Naijiria.

"A ko lee faaye gba isẹlẹ bii ki ilẹkun baalu maa sadede foyọ. Ile asofin agba yoo sisẹ lori isẹlẹ yii. Iru rẹ ko gbọdọ tun sẹlẹ mọ."