Ilẹkun Baalu Dana fo yọ nilu Abuja

Ilẹkun ọkọ ofurufu Dana to fo yọ Image copyright Dapo Sanwo
Àkọlé àwòrán Ilẹkun ẹyin lawọn ero inu baalu Dana naa gba jade nigbati ilẹkun iwaju ja bọ

Ọpọ ero to wa inu baalu Dana lọjọbọ lo n se ọpẹ pe ori ko wọn yọ lọwọ ewu nigbati ilẹkun iwaju baalu B45 to ko awọn ero lati ilu Eko lọ si Abujas sadede fo yọ ni kete ti baalu naa balẹ tan nilu Abuja.

Gẹgẹbi ẹnikan ti isẹlẹ naa soju rẹ, Ọgbẹni Dapọ Sanwo ti fidi isẹlẹ naa mulẹ fun ileesẹ BBC, o ni ariwo lasan lawọn kan gbọ to gbalẹ kan ninu baalu naa, to si n mi laimọ pe ilẹkun iwaju naa lo fẹ fo yọ.

Ọgbẹni Sanwo ni ni kete ti baalu naa balẹ, ni ilẹkun yi sadede fo yọ funra rẹ, lai jẹpe ẹnikẹni tii fọwọ kan-an, eyi to mu kawọn ero inu baalu naa gba ilẹkun ẹyin jade.

Ẹ gbọ alaye Dapọ Sanwo siwaju si lori isẹlẹ yi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBayo Sanwo salaye lori ilẹkun baalu Dana to fo yọ nilu Abuja

Ọpọlọpọ awọn eeyan to wa ninu baalu Dana naa lasiko isẹlẹ yi si lo ti n fi oniruuru iroyin sọwọ sori opo ikansiraẹni twitter wọn .

Wayi o, ileesẹ ofurufu Dana ti wa sẹ kanlẹ pe ilẹkun baalu awọn kankan ko ja bọ rara.

Iroyin kan ti ileesẹ ọkọ ofurufu Dana gbe soju opo Twitter rẹ ni ilẹkun baalu wuwo, to si mulẹ debi pe ko lee da si, tabi jabọ funra rẹ lai jẹ pe ẹnikẹni fi ọwọ kan-an.